EFCC vs Naira Marley: Nítorí ẹ̀sùn 'yahoo-yahoo' Adájọ́ ní kí Naira Marley ó máa gbatẹ́gùn láhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n

Naira Marley Image copyright EFCC

Adajọ to n gbẹjọ olorin takasufe kan lorileede Naijiria, Naira Marley lori ẹsun ''Yahoo Yahoo'' ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi si ahamọ titi di igba ti wọn yoo fi gbẹjọ rẹ.

Lowurọ ọjọ aje ni Adajọ ile ẹjọ giga ni Ikoyi, Onidajọ Nicholas Oweibo ni o di ọgbọnjọ osu kaarun ọdun 2019 ki wọn to le gbẹjọ lori ẹbẹ fun gbigba oniduro rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka loju opo Facebook ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC, ẹsun mọkanla ni wọn fi kan Azeez Adeshina, ti gbogbo eeyan mọ si Naira Marley.

Ẹsun mọkanla ni wọn fi kan an; gbogbo mẹwẹẹwa lo si fesi si pe oun ko jẹbi wọn.

Ni ọjọ kẹwa oṣu karun ni awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC gbe Naira Marley lẹyin ọpọlọpọ ifimufinlẹ lori bi o ṣe n lẹdi apo pọ pẹlawọn ti o n lu jibiti lori ayelujara.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Naira Marley ni pe: 'Iwọ, Azeez Adeshina ti inagijẹ rẹ n jẹ Naira Marley, ati Yad Isril (ti o ti na papa bora), gbimọ pọ ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2018 lati lo kaadi ti numba rẹ jẹ 5264711020433662 eyi ti kii ṣe tiyin lati fi gba nnkan lọna aitọ. Eleyii to tako abala keje ofin ti o n gbogun ti iwa ọdaran ori ayelujara tọdun 2015 (the Cybercrime Prohibition, Prevention etc Act 2015 )

Bi agbẹjọro fun olupẹjọ ṣe n rọ adajọ ile ẹjọ naa lati fun wọn ni ọjọ ti igbẹjọ gan an yoo bẹrẹ ni agbẹjọro Naira Marley n beere fun ọjọ lati gbọ ẹjọ lori ẹbẹ rẹ fun gbigba oniduro rẹ.

Eyi lo mu ki Onidajọ Oweibo o kede Ọgbọn ọjọ oṣu karun ọdun 2019 fun gbigbọ ẹjọ lori boya ki wọn gba oniduro rẹ titi ti igbẹjọ yoo fi maa waye.

Laipẹ yii ni ariwo Naira Marley gbode kan lori ikanni ayelujara gbogbo lori awọn ọrọ to n sọ lati fi kan sara sawọn to n fi ẹrọ ayelujara lu jibiti.

Bi aje ẹsun yi ba ṣi mọ Naira Marley lori, o lee fi ẹwọn ọdun meje jura tabi ki o san owo itanran to to miliọnu marun naira.