Lagos rain: Ilé méjì, ọ̀pọ̀ igi àti òpó iná wó lẹ́yìn òjò tó rọ̀ nílùú Eko

Igi wo lu awọn ọkọ nilu Eko Image copyright @lasemasocial
Àkọlé àwòrán Ajọ LASSEMA ni ọpọ ọṣẹ ni o ba ojo naa kọwọrin, awọ̀n ko si tii le sọ iye ọṣẹ to ṣe ni pato

Ojo to rọ lọjọ aje ni ilu Eko ti da ṣugbọn ọwọja rẹ ati ipa ti o fi silẹ ṣi n ja ranyinranyin.

Yatọ si pe ọpọ wakati ni awọn olugbe ilu Eko lo ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ fun ọpọ wakati nitori ojo ọhun ọpọlọpọ ọṣẹ miran ni ojo oniwakati meji naa ṣe lasiko ti o fi da ti inu rẹ kalẹ sori ilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkójọpọ̀ àwòrán Òjò òwúrọ̀ Ọjọ Àjé l'Eko

Èèmọ̀ rèé o! Òkú ọmọ tuntun pòórá nílé ìgbókúpamọ́sí nílùú Akurẹ

Ọwọ iji lile ti ojo naa, eyi to bẹrẹ ni nnkan bii agogo mẹjọ abọ mu dani, to si jẹ pe, ile meji lo wo, ọpọlọpọ igi ati opo ina lo si wo lulẹ.

Image copyright @lasemasocial

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ilu Eko, LASSEMA ṣalaye pe skan lara ile to wo naa wa ni agbegbe Abule ẹgba, ti omiran si tun wo lulẹ lagbegbe Ladipo Busstop, ni Oshodi.

Image copyright @lasemasocial

Bakan naa ni ajs naa tun ṣalaye pe awọn igi to wo ọhun tun wo lu awọn ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wsn si tun da wahala irinna silẹ.

Image copyright @lasemasocial

Amọṣa ajs naa ni iṣẹ ti n lọ lati ko gbogbo awọn igi ti o wo kuro loju popo.

Àkọlé àwòrán Gbogbo oju popo lo kun fun omi
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọkọ ni ojo naa tun bajẹ

Bakan naa ni ojo ọhun ko ṣai tun da ọpọ iṣẹ ijọba lara.

Fun apẹrẹ, ajọ ẹṣọ oju popo lorilẹede Naijiria, FRSC ti wọn ti kede ọjọ aje gẹgẹ bii ọjọ ti wọn yoo bẹrẹ akanṣe eto kan lori fifi iwe aṣẹ iwakọ han, 'Show your Drivers Licence' ni ipinlẹ Eko lọjọ aje ko lee bẹrẹ rẹ nitori awọn gan ko gbẹyin ninu ṣiṣeranwọ lori ki irinna ọkọ lee ja geere.

Image copyright @lasemasocial

Related Topics