Snake bite: Ejò sàn adájọ South Africa tó lọ gbàfẹ ni Zambia pá

aworan ejo Image copyright SPL
Àkọlé àwòrán Aworan ejo irufẹ eleyi to pa adajọ naa

Adajọ ile ẹjọ ọrọ oṣiṣẹ kan lorileede South Africa Anton Steenkamp ti ko agbako iku lẹyin ti ejo kan san an jẹ lasiko to lọ gbafẹ lorileede Zambia.

Ẹni ọmọ ọdun mẹtadinlọgọta nii ṣe.

Mọlẹbi rẹ kan Ruby Steenkamp sọ fun ile iṣẹ iroyin News24 pe ''iku rẹ ba wa lojiji. Eeyan ni. Iyawo rẹ Catherine n bọ lọna lati wa si Zambia. Awọn mejeeji jijọ n ṣe irinajo inaju ni.''

Akọroyin kan lorileede South Africa Max du Preez gbosuba fun adajọ Steenkamp to si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ''ọlọgbọn eeyan, alaanu, ti a le fi ọkan tan''

Related Topics