'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Abiodun Koya: Láti ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti ń kọrin bi ẹyẹ

Abiodun Koya jẹ akọrin ọmọ Naijiria to ni ohun gooro fun awọn orin bii ti igbaani tabi paapaa julọ awọn orin ti wọn ki lu ilu si.

O tun jẹ akọ ewi to n gbe nilẹ Amẹrika.

O jẹ ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ akọrin olohun gooro perete to orisun wọn jẹ ilẹ Afirika. Wọn a maa pe e ni akọrin f'ọba, fun aarẹ atawọn adari orilẹede.

Abiodun Koya ti gbe orin olohun gooro rẹ de ile ijọba ilẹ Amẹrika (White House). Irawọ rẹ bẹrẹ si ni tan nigba to wa ni ile iwe rẹ ni Washington DC nibi to ti kọkọ kọ nipa ẹkọ katakara ko to lọ kọ nipa ẹkọ orin kikọ.

O ti kọ orin kaakiri agbaye fun awọn ọlọla, aarẹ, mọlumọọka o si ni afojusun fun ọjọ iwaju ẹya iru orin to n kọ.