Temidayo Adeleke: Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n yẹgi fún ọmọ Cameroon tó pa ọ̀gá rẹ̀ ni Ikoyi

Dayo Adeleke ti alase rẹ ṣeku pa ni 2016

Odindi ọdun meji ati aabọ ni igbẹ́jọ lori bi ọmọ Cameroon kan ṣe sẹku pa ọga rẹ Dayo Adeleke, ni oṣu kejila ọdun 2016, ṣugbọn ni ọjọ Iṣẹgun, ile ẹjọ agba kan ni Ipinlẹ Eko ti dajọ iku fun Leudjoe Koyemen Joel.

Ninu igbẹjọ naa, adajọ Adedayo Akintoye ni Joel jẹbi ẹsun pe o pa Adeleke ni ile rẹ to wa ni Parkview Estate, Ikoyi, lẹyin ti arabinrin naa ran an lọwọ lati fun ni iṣẹ.

Adajọ Akintoye ni ki wọn yẹgi fun Joel.

Báwo ni Joel ṣe ṣe iku pa ọga rẹ?

Alẹ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lọjọ naa lọhun. Adeleke jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn nigba naa. Oṣu meji ṣaaju igba naa, arabinrin naa gba Joel sile lati di alase rẹ lai mọ pe iku ni oun gba sinu ile.

Iroyin ni, Joel jẹ atipo lati orilẹede Cameroon ti ijọ kan ran lọwọ nigba to kọkọ wọ Naijiria. Adari ijọ naa ni a gbọ pe o rọ Adeleke pe ki o ran ọmọkunrin naa lọwọ lati gbaa gẹgẹ bii oluranlọwọ inu ile.

Ni ọjọ buruku naa, adajọ ni, oun to bi Joel ninu ni wipe, Adeleke sọ fun ọmọkunrin naa wipe oun ko le san owo ọsẹ meji eyi ti ko tii ṣiṣẹ rẹ fun.

Image copyright William Smith/Instagram
Àkọlé àwòrán Fidio kan ṣe afihan ibi ti afẹsunkan naa ti n jo lẹyin to pa ọga rẹ.

Fidio kan ṣe afihan ibi ti afẹsunkan naa ti n jo lẹyin to pa ọga rẹ lori atẹ Instagram rẹ ninu eyi to ti n jẹ inagijẹ Wil.iam Smith.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'

'Afẹsunkan gba anfani igbeyawo, ọmọ bibi ati ẹmi gigun lọwọ ọga rẹ'

Adajọ ni bi Joel ṣe pa alaanu rẹ, oo gba anfani igbeyawo, ọmọ bibi ati ẹmi gigun lọwọ Adeleke. Iroyin fi han wipe ọjọ igbeyawo arabinrin ku diẹ nigba ti alase rẹ naa ṣe iku pa.

Elomiiran ti oṣiṣẹ inu gun pa ni Parkview Estate

Yatọ si Adeleke, ni Parkview Estate yii naa, ọmọ orilẹede Togo kan to jẹ alase gun ọga rẹ Oloye Opeyemi Bademosi pa ni ile rẹ to wa ni Onikoyi Lane, Parkview Estate ni oṣu kẹwaa ọdun 2018.

Ọjọ kẹta lẹyin ti wọn gba Sunday Anani, si iṣé ni o fi ọbẹ gun ọga rẹ pa ti o si ko awọn dukia ọga rẹ salọ.

Image copyright Ope bademosi/facebook.com
Àkọlé àwòrán Àwọn ọlọpàá sọ wípé ọmọ̀ ọ̀dọ̀ Sunday Adefonou Anani ti jẹ́wọ́ pé òun ló pa ọ̀ga rẹ̀, Ọpẹ Bademọsi, tó wà nínú àwọran yìí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌlọ́pàá Ondo: A bá òkú ọmọ igbákeji gómínà tẹ́lẹ̀rí nílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀