NASS media coverage: À n ṣe àgbéyẹ̀wò ìlànà túntún fún àwọn akọ̀ròyìn

Ami idanimọ ile aṣofin Naijiria Image copyright Getty Images

Awọn alasẹ ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria ti ṣe atungbeyẹwo awọn ofin ati ilana ti awọn akọroyin ti yoo ṣiṣẹ nile aṣofin kẹsan gbọdọ tẹle.

Agbẹnusọ fun ile aṣofin, Emmanuel Agada, sọ fun BBC pe awọn ti bẹrẹ si ni ṣe ayẹwo awọn ilana ti yoo mu ko ṣeeṣe fun wọn lati yanju awọn awuyewuye to n jẹyọ lori iṣẹ awọn akọroyin.

Ṣaaju ni Ọgbẹni Agada fi ikede kan sita pe lọgan ti ile aṣofin kẹjọ ba wa sopin ni aṣẹ ti awọn akọroyin n lo fi ṣiṣẹ nile aṣofin naa wa sopin, ati pe akọroyin to ba fẹ ẹ ṣiṣẹ nile aṣofin kẹsan an gbọdọ tun orukọ fi silẹ.

Ṣugbọn, awọn akọroyin n fi ẹhonu han pe ọgbọn lati di ọna mọ ominira awọn oniroyin ni igbesẹ naa.

Eyi si lo mu ki awọn alaṣẹ ile aṣofin tun awọn ilana naa yẹwo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'

Kilo fa awọn ilana tuntun ?

Ọgbẹni Agada sọ pe lati asiko diẹ sẹyin, ọpọlọpọ onijibiti eniyan lo ti wọ ile aṣofin wa, ti wọn si n pe ara wọn ni akọroyin.

O sọ pe pupọ ninu wọn yoo kan darukọ ileeṣẹ iroyin to ba wu wọn, lati le ni anfaani lati wọ ile aṣofin lati tọrọ owo, jale tabi yẹyẹ awọn aṣofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Nígbà tí mò ń wà Awolowo, Gowon, Babangida, mo fi ara mi sípo ọ̀wọ̀ tóri ...'
Image copyright AFP

'A ni ju igba akọroyin lọwọlọwọ to n ṣiṣẹ nile aṣofin, eyi si ti mu ki eero o pọju nile aṣofin."

Bakan naa lo fi kun pe ilana tuntun naa yoo mu ki eto aabo ko fẹsẹ mulẹ daada nile aṣofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTọkọ-taya Aràrá: Àwọn èèyàn máa ń wò wá, ta bá fa ọwọ́ ara wa ní títì

Awọn nkan wo lo wa ninu ilana tuntun naa?

Ofin ogún ni awọn alaṣẹ la kalẹ fun gbogbo akọroyin lati maa tẹle, diẹ lara wọn niyii:

 • Ẹri pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ akọroyin ni Naijiria, NUJ
 • Iwe ẹri lati ọdọ ile iyawe-kawe apapọ Nigeria (National Library of Nigeria)
 • Ileeṣẹ iwe iroyin to n ba a ṣiṣẹ gbọdọ maa pin ogoji ẹgbẹrun iwe iroyin lojoojumọ
 • Aadọta ẹgbẹrun eniyan gbọdọ maa bẹ oju opo ayelujara iwe iroyin ori ayelujara wo lojumọ, iwe iroyin bẹ si gbọdọ ti wa fun ọdun maarun
 • Iwe ẹri owo ori ọdun meji fun ileeṣẹ iroyin rẹ
 • Ileeṣẹ iroyin rẹ gbọdọ ni ọọfisi si ilu Abuja, o si gbọdọ ni oṣiṣẹ ti ko din ni maarun
 • Ileeṣẹ amohunmaworan ti wọn n wo jake-jado Naijiria tabi ogbontagi oniroyin nikan ni yoo ni anfaani lati ṣiṣẹ nile aṣofin apapọ
 • Akọroyin gbọdọ ni iriri ọdun meji lori ọrọ ile aṣofin

Ẹgbẹ oniroyin, NUJ, koro oju si awọn ilana tuntun naa

 • Ẹgbẹ oniroyin (NUJ), ẹgbẹ awọn olootu iroyin, ati awọn oniroyin mi i ti bu ẹtẹ lu awọn ilana tuntun yii. Wọn ni awọn alaṣẹ ile aṣofin fẹ ẹ dena ominira awọn oniroyin ni.
 • Ẹgbẹ NUJ ti fun awọn alaṣẹ naa ni gbedeke wakati mẹrinlelogun lati yi ofin naa pada
 • Ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2019 ni lilo ofin tuntun naa yoo bẹrẹ
 • Amọ ṣa, Ọgbẹni Agada ti sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ lori bi ofin tuntun naa ko ṣe ni i ṣe idiwọ fun iṣẹ awọn akọroyin.

Related Topics