Ọkọ̀ akérò BRT gbiná lórí afárá 3rd Mainland

Ọkọ̀ BRT Image copyright @AlliAdekola @chuachebe @StockmanNigerian
Àkọlé àwòrán Ọkọ̀ BRT

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ọkọ̀ akérò ńla kan tí wọ́n mọ̀ sí BRT nípinlẹ̀ Eko ń jóná lórí afárá 3rd Mainland.

Eyi ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lori afara naa.

Ẹwẹ, iroyin ti tẹ wa lọwọ pe awọn oṣiṣẹ panapana ti de bi iṣẹlẹ naa ti wọn si ti pa gbogbo ina to n jo.

Boya ẹnikẹni ba iṣẹlẹ yi rin tabi bẹẹ kọ ko tii ye.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.