Apapa Gridlock: Ààrẹ Buhari ti pàṣẹ kí wọ́n ó kó àwọn ọkọ̀ kúrò láàrin ọjọ́ díẹ̀

Awọn ọkọ akẹru to di oju ọna Apapa

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn o ko gbogbo awọn ọkọ nlanla to wa ni papakọ oju omi Apapa kuro laarin ọsẹ meji pere.

Aṣẹ naa n fẹ ki wọn o ko gbogbo awọn ọkọ akẹru ti wọn wa gunlẹ si awọn ojupopo ati ori afara to wa ni Apapa ati awọn agbegbe to wa nitosi rẹ kuro.

Lati le mu ki eyi o ṣeeṣe , ijọba ti paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ to ni ọkọ akẹru ati ọkọ agbepo lati ko ẹru wọn kuro ni awọn oju ọna to wọ ibudokọ oju omi naa laarin wakati mejilelaadọrin.

Aṣẹ yii waye lẹyin ipade pajawiri ti Aarẹ Muhammadu Buhari ati Igbakeji rẹ, Yẹmi Ọṣinbajo ṣe lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn èèyàn àti awakọ̀ ké igbe ìrora bí àwọn ọkọ̀ ńlá ṣe dí ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Apapa-Oshodi pa

Nibi ipade naa ni wọn ti ri ọna abayọ ti yoo yanju sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ to n waye ni awọn ibudokọ oju omi l'Eko, eyi to n se akoba fun igbeaye awọn eniyan l'agbegbe naa.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni asoju awọn ileeṣẹ ijọba ti ọrọ kan, lajọ-lajọ, Minisita fun ipese ina, iṣẹ ode ati ilegbigbe, Babatunde Raji Faṣhọla; Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Mohammed Adamu; Akọwe Agba nileeṣẹ to n risi eto irinna nipinlẹ Eko, ati Oludari Agba fun igbokegbeodo ọkọ ori omi, ati ileeṣẹ to n mojuto ibudokọ oju omi ni Naijiria, Ọmọwe Sokonte Davies.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwakọ̀ 3rd Mainland Bridge: Ìjọba ko yanjú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọ̀nà Apapa

Iṣoro nla ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ n ko o ba awọn to n gbe ni agbegbe Apapa, ti wọn si n fi ojoojumọ fi ibanujẹ han lori awọn ọna ti ko dara.

Igbakeji Aarẹ, Ọṣinbajo ni alaga ikọ̀ amuṣẹya ti yoo ri si bi eto irinna ọkọ̀ yoo ṣe pada sipo ni oju ọna naa.

Ikọ̀ naa yoo si maa ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa, Ẹgbẹ awọn ọkọ akẹru, ati ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ̀ nipinlẹ Eko (LASTMA) lati ri i daju pe aṣẹ naa fidimulẹ.

Bakan naa ni ijọba ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ ogun ori omi ati awọn ọmọ ologun mi i to n dari ọkọ̀ nibẹ dawọ iṣẹ duro, ki wọn o si ko awọn ibudo ti wọn ti n da ọkọ̀ duro fun ayẹwo kuro.

Related Topics