Wo àwọn ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ajọ àwọn gomina Naijiria

Gomina Kayode Fayemi Image copyright Twitter/Kayode Fayemi
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ awọn gomina Naijiria

Gomina Ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ni alaga tuntun awọn gomina lorilẹ-ede Naijiria bayii.

Lalẹ Ọjọru ni Fayemi di alaga tuntun awọn gomina lẹyin idibo- afọwọ sii to waye nibi ipade awọn gomina lolu-ilu Naijiria, Abuja.

Fayemi to jẹ minisita tẹlẹ fun ẹka iwakusa ati irin ni ibo to le ni ida aadọrin lati jawe olubori ninu ibo ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayode Fayemi : Awọn osisẹ ni Ekiti ko i tii gba owo osu ni ọdun yii

Gomina Ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, ati ti Delta, Ifeanyi Okowa lo fa Fayemi kalẹ fun didije ninu idibo naa.

Gomina Abdul Aziz Yari lati ipinlẹ Zamfara lo ju awà silẹ lẹyin to ti tukọ ajọ naa lẹẹmeji laarin ọdun mẹrin

Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ni igbakeji fun Fayemi ninu ajọ awón gomina lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀ ní kété tó di gómìnà Ekiti

Gomina Fayemi yoo gbajọba lọwọ Gomina ipinlẹ Zamfara Abdul-aziz Yari Abubakar ti ijọba rẹ tan lalẹ Ọjọru.

Saaju ni gomina Dickson tipinlẹ Bayelsa ti ni awọn gomina lati ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni dije dupo alaga naa lasiko yii.

Ni kete ti wọn yan Fayẹmi tan lo ti parọwa fawọn akẹgbẹ rẹ lati tubọ mojuto ọrọ eto aabo Naijiria to ti n gbẹbọ lọwọ koowa bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayode Fayemi fi iwe eri moyege han Aare Buhari

Ohun to yẹ koo mọ nipa ajọ gpmina Naijiria

Ọdun 1999 ni wọn da ajọ awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria silẹ.

Wọn daa silẹ pẹlu erongba pe ki awọn gomina le maa mojuto ohunkohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria bẹrẹ lati ipinlẹ koowa wọn.

ọpọ igba ni igbesẹ ajọ awọn gomina yii maa n yatọ si ti ijọba apapọ bii aifẹnuko lori odiwọn iye owo ọya awọn oṣiṣẹ eyi to yatọ lati ipinlẹ kan si ikeji.

Lọwọlọwọ ni ẹnu wọn kò kò lori sisan owo sapo awọn alaga ijọba ibilẹ bi o ti yẹ ni eyi tijọba apapọ ṣẹṣẹ fẹ mojuto lasiko yii.

Lọdun 2017 ni wọn tun forigbari nigba ti ajọ EFCC to n risi ọrọ ṣiṣe owo ilu ni mọkumọku fẹ tojubọ bi wọn ṣe n na owo iranwọ ojiji ti Paris Club tijọba apapọ pin fun wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFayẹmi: Ọ̀pọ̀ èèkàn ìlú ló bá se ayẹyẹ ìbúra

Kinni o mọ nipa Kayode Fayemí?

Kayode Fayemi jẹ ọmọ Ilu Isan-Ekiti ni ijọba ibilẹ Oye nipinlẹ Ekiti.

Ọjọ kẹsan an, oṣu keji, ọdun 1965 ni wọn bi Ọmọwe Fayemi.

Fayẹmi ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ kaakiri ilẹ Afirika, Yuropu, Amẹrika ati ilẹ Asia.

Fayemi jẹ Gomina ipinlẹ Ekiti lọdun 2010 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria (ACN).

Ọmọwe Fayẹmi tun ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi oniroyin, oniṣẹ iwadi ati olugbani-nomọran lori ọrọ idagbasoke tẹlẹ ri.

Fayemi gẹgẹ akọkọ ni ilẹ iwe giga fasiti Ilu Eko(UNILAG), bẹẹ lo gba oye keji ni fasiti Ile Ife.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionContortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

Fayemi gba oye Ọmọwe ni Fasiti Kings College niluu London.

O ṣe igbeyawo pẹlu Olabisi Fayemi, wọn si bi ọmọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Kọmisana feto idibo ni ibo kika si n lọ lọwọ