Ọwọ́ tẹ ọkunrìn tó n fi kẹ́míkà ṣe ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ àti ibà.

Awọn ọmọlẹyin Kristi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Oríṣiríṣi nkan bí ìwé ìrìnnà sílẹ̀ òkèèrè ni àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Uganda ma n gba àdúrà fún

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Britain kan, to n pin kẹmika to n yọ idọti 'bleach' fun awọn eniyan gẹgẹ bi omi iyanu.

Ọwọ ọlọpaa orilẹ-ede Uganda tẹ Sam Little, ati ọmọ orilẹ-ede Uganda meji: Sauel Albert, ati Samula Tadeop ni Ọjọbọ niluu Fort Portal lorilẹ-ede naa.

Wọn fi ẹsun kan awọn ọkunrin mẹtẹẹta ọhun pe wọn fun awọn ọmọ orilẹ-ede Uganda kan ni kẹmika ti wọn ṣe latara 'Chlorine Dioxide'.

Kẹmika yii jẹ eyi ti awọn ileeṣẹ fi n yọ idọti ninu eyi to hande pe wọn pe e fun wọn ni Omi iṣẹ iyanu, ti wọn si ni o n wo aisan bi i jẹjẹrẹ ati ibà san lara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWoli Kasali: Angẹli mi ni orékelẹ́wà Dọlapo Awoṣika

Ọgbẹni Little ti sọ ọ ri pe oun n ran awọn ọmọ Uganda lọwọ nipa pipese iwosan olowo pọọku fun wọn.

Sugbọn, ko ti i sọ ohunkohun lati igba ti awọn ọlọpaa ti mu u.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNínú sọ́ọ̀sì, wọ́n ń sáré lọ síwájú fún ìwòsàn sùgbọ́n lẹ́yìnkùlé,...

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ba igbó ati omi iyanu naa nile rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Wọn ti fi ofin de omi iyanu naa ni ọpọlọpọ orilẹ-ede, wọn si ni o n fa eebi, ati aisan inu ẹjẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kesi awọn to ti gba omi iyanu naa lati yọju sita fun ẹrí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"