Facebook yóò bẹ̀rẹ̀ ìnáwó orí ayélujára 'GlobalCoin' lọ́dún 2020

facebook Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ayelujara nla naa yóò bẹ̀rẹ̀ ìnáwó orí ayélujára to jẹ ti ara rẹ

Facebook ti n gbero lati gbe eto iṣuna ori ayelujara, Crypto-currency jade ni ọdun to n bọ.

Eto naa wa lati mu eto sisan owo lori ikanni igbalode ṣeeṣe lawọn orilẹ-ede mejila kan nigba ti a o ba fi ri oṣu mẹta akọkọ lọdun 2020.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ ayelujara naa fẹ bẹrẹ si nii gbe owo ori ayelujara tirẹ, eyi to pe orukọ rẹ ni Global Coin yẹwo ni opin ọdun yii.

Facebook ti n ba gomina banki ilẹ Gẹẹsi, Mark Carney fikunlukun lori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo ọna ti o le gba lati fi daabo bo ara rẹ lori Facebook.

Oludasilẹ Facebook, Mark Zuckerberg ṣe ipade pẹlu Ọgbẹni Carney loṣu to kọja lati jiroro lori awọn anfani to wa ninu eto naa ati awọn wahala to lee ti inu rẹ jẹyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Facebook tun ti gba imọran lori awọn ohun to nii ṣe pẹlu ofin ati ilana eto iṣuna ori ayelujara naa lọdọ awọn adari eto iṣuna ilẹ Amẹrika.

Bakan naa lo tun n ba awọn ileeṣẹ agboworin ori ayelujara kan bii Wester Union sọrọ nitori awọn ọna olowo pọọku ati ayarabi aṣa ti o n wa fun awọn eeyan ti ko ni apo ifowopamọsi lati fi owo ranṣẹ tabi gba owo.

Facebook fẹ da owo ori ẹrọ kọmputa silẹ eyi ti ko ni ga ju ara lọ ti yoo tun pese abo to peye fun awọn ina isanwo lori ayelujara lai naani boya ẹni bẹẹ ni aṣuwọn ifowopamọsi ni banki tabi ko ni.

Eto ọhun ti wọn da pe ni Project Libra eleyi ti facebook n gbero rẹ yii yoo wa bọ si gbangba ni oṣu kejila ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLábẹ́ odò! Ìgbéyawó yìí lárinrin

Szu Ping Chan