Adamawa: Ọlọ́pàá mú ẹyẹ igún sí àtìmọ́lé ní ìpínlẹ̀ Adamawa

Ẹyẹ igun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ṣi n ṣewaadi ẹsun ti wọn fi kan ẹyẹ igunnugun naa

Ile iṣẹ ọlọpaa ni #30, 000 ($86, £67) ni awọn fi bọ igun naa ati olowo rẹ laarin ọjọ mẹfa to fi wà ni atimọle.

Agbegbe Maiha nipinlẹ Adamawa ni wọn ti mu ẹyẹ igun naa gẹgẹ bii afurasi pé o n ṣalamí fawọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram.

Oga agba ọlọpaa Othman Abubakar, to tun jẹ alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Adamawa ni owo ti awọn fi n bọ igun yii ko ba pọ sii ka ni awọn ṣi fi si atimọle.

Oga ọlọpaa ni iṣẹ iwadii naa ṣi n lọ lọwọ nitori awọn olugbe agbegbe Mahia n fura si obinrin to ni ẹyẹ igun naa.

Baba agba kan nilu naa ni igba ikẹyin ti ẹnikan mu ẹyẹ abami igun yii wa si agbegbe wọn ni Boko Haram.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFFK: Buhari ló ń fún àwọn Fulani láàyè láti máa pa ènìyàn'

Awọn ẹgbẹ ti wọn n ja fun itọju nkan ayika ati nkan adayeba ni Naijiria ti n sọ fun awọn agbofinro lati tu igun yii silẹ.

Báwo ni ọwọ́n ṣe mú igún náà satimọlẹ ṣaaju iwadii?

Kayefi nla leyi ṣugbọn ododo ọrọ ni. Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Adamawa ti mu ẹyẹ igun kan si atimọle bayii ni ipinlẹ naa.

Oniruuru iroyin lawọn eeyan n gbe lori ẹyẹ igun naa ati ohun to gbe e de atimọle. Bi awọn kan ṣe n wi pe ẹyẹ naa nii ṣe pẹlu ikọ agbebọn Boko haram ni wsn ṣe muu lawọn miran n pe arakunrin kan ni o yipada di igun naa lati maa da awọn alabagbe rẹ laamu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Nígbà tí mò ń wà Awolowo, Gowon, Babangida, mo fi ara mi sípo ọ̀wọ̀ tóri ...'

Amọ ṣa ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ọlọpaa fun ipinlẹ Adamawa, Othman Abubakar ṣalaye pe lootọ ni awọn eeyan kan lati ijọba ibilẹ Maiha fi ẹjọ sun awọn pe eeyan kan to wa ni ahamọ ọlọpaa ti yirapada di ẹyẹ igunugun eleyii ti o n wa si ile ati ilu wọn lati da wọn laamu.

Ọga ọlọpaa Abubakar tun ṣalaye siwaju sii pe, ko si ootọ ninu ọrọ naa nitori pe ọkunrin ti wọn ni o n yirapada naa ṣi wa ninu atimọle, ṣugbọn awọn ti lọ mu ẹyẹ igun ti wọn n sọ naa wa si ahamọ.

O ni ati ẹyẹ igun, ati ẹni ti wọn n pe o yirapada sii ni wọn jijọ wa ni atimọle bayii.

O ni iwaadi ṣi n lọ lori ọrs naa ṣugbọn ko si otitọ ninu ọrọ ti awọn eeyan naa n sọ pe arakunrin ọhun ti poora kuro ni ahamọ ọlọpaa, o si ti yirapada di ẹyẹ igunugun ti n da araalu laamu