May 29 Inauguration: Minista mẹ́fà tí kò tẹ́ àwọ ènìyàn lọ́rùn

Àkọlé àwòrán ẹ ko gbiyanju tó ni saa kinni Buhari loju wa

Aarẹ Buhari to n tukọ Naijiria lati 2015 ti ṣeto idagbere fawọn minista ti wọn jọ ṣiṣẹ.

Aarẹ ki gbogbo wọn ku iṣẹ takuntakun ṣugbọn ọpọ ninu awọn ọmọ Naijiria lo n binu si diẹ ninu awọn minista naa pé wọn ko ṣe daadaa tó.

Buhari ni ki gbogbo minista ju awa iṣẹ wọn silẹ fawọn akọwe agba ile iṣẹ ijoba apapọ ti ẹni kọọkan wọn n ṣe minista le lori.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Ọpọ ojo lo ti rọ tilẹ ti fi mu ni iṣẹ awọn minista ti wọn ba Buhari ṣe ijọba lọdun mẹrin to n kogba wọle yii.

Awọn ara ilu ti wi nkan oriṣii si awọn minsta yii lataari ihuwasi, ọrọ ẹnu wọn ati ohun to ṣẹlẹ ni ile iṣẹ ijọba apapọ ti wọn n mojuto.

Ibura Buhari ni Saa iṣejọba keji

Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni wọn yoo ṣe ibura fun Aarẹ Buahri to tun jawe olubori lẹẹkeji gẹgẹ bii aarẹ Naijiria.

Wọn ti ni ayẹyẹ ibura fun ni naa ko pọ pupọ lọtẹ yii ni Abuja.

Diẹ lara awọn minista ti awọn eniyan sọrọ julọ laida nipa wọn ni:

Solomon Dalung- Minista fun ọrọ ọ̀dọ́ ati ere idaraya

Image copyright @solomon
Àkọlé àwòrán Oun lo kọkọ koju iṣoro ibere ta ni adari ajọ NFF ni Naijiria?

Minista yii lo kọkọ fi ọrọ ajọ to n mojuto eto ere bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, NFF ṣide iṣẹ nigba to wọle.

Oun lo kọkọ koju iṣoro ibeere ta ni adari ajọ NFF ni Naijiria? Amaju Pinnick di ààrẹ àjọ NFF tuntun

Victor Moses, Oshoala gba ami ẹyẹ Wahala rẹ pẹlu Amaju Pinnick ati Chris Giwa lo jẹ ki ajọ elere bọọlu lagbaye, FIFA kuku fofin de Naijiria ati ere bọọlu alafẹsẹgba ki Yẹmi Oṣinbajo igbakeji aarẹ to da sii.NFF sadehun pẹlu Dennerby fun Falcons

Labẹ iṣakoso rẹ ni awọn ẹka ere idaraya ti n ni adari meji bii eyi to n ṣẹlẹ lọwọ lẹka ere bọọlu alajusawọngba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnigbinde àti Owolabi: Ààrẹ NFF tuntun gbọdọ̀ sàwárí ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ agbábọ́ọ́lù

Iṣorọ mii tawọn eniyan ko tun fi gba ti ẹ ni bii ti eyi ti ajọ elere sisa Naijiria ko tii rẹnu ṣalaye ohun ti wọn fi ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla ilẹ okeere ti ajọ elere sisa agabye ṣeṣi san sinu asunwọn banki wọn.

Adebayo Shittu: Minista fun ibanisọrọ

Oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn fi kan minista yii ni kete to ti gbe igba ibo lati dije dupo gomina ipinlẹ Oyo ninu saa yii.

Image copyright @Shittu
Àkọlé àwòrán O wu mi lati tukọ ipinlẹ Oyo

Ọpọ gba pe oun naa ko ni iwe ẹri agunbanirọ lati fi sọ pe oun sin ilẹ baba oun bii ti Kemi AdeosunAPC yọ orúkọ Shittu kúrò láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé.

Awọn mii ni awon ko ri laarinja iṣẹ to ṣe yanju Nàìjíríà fẹ́ yá $100m lọ́wọ́ India fún ìtàkùn àgbáyéni ẹka ile iṣẹ ijọba apapo to moujto naa.

Oun naa sọrọ oṣelu aini ibadọgba anfani ninu ẹgbe nigab ti ko pada ri tikẹẹti lati dije dupo gomina Oyo'Ó ku Shittu, ó ku Ọlọ́run lórí ohun tó fẹ́ fi san ẹgbẹ́ APC l'ẹ́san'

Chris Ngige: Minista fun igbode iṣẹ

Image copyright @NGF
Àkọlé àwòrán Ọkan lara awọn ọna naa ni eyi to sọ laipẹ lori awọn oniṣegun oyinbo ti wọn sa kuro ni Naijiria lasiko yii.

Ọpọ igba lorukọ rẹ ti jade pẹlu eebu to pọ lori ẹrọ ayelujara lori ọrọ ẹnu rẹ.

Ọkan lara awọn ọna naa ni eyi to sọ laipẹ lori awọn oniṣegun oyinbo ti wọn sa kuro ni Naijiria lasiko yii.

Ọpọlọpọ iyanṣẹlodi Ìpàdé ìjọba ati ASUU forí sánpọ́n, ifẹhonuhan Àwòrán ìwọ́de NLC, TUC, ULC lónìí ati NLC, TUC: Àwa ò gba owó lọ́wọ́ Fayose ooo ileri titi ilẹkun ọrọ aje Kíni ìdí tí NLC fi kọ N27,000 owó osù òsìsẹ́? ni o ṣẹlẹ ninu ọdun mẹrin ti Ngige fi ṣe minista yii.‘ASUU da ìyanṣẹ́lódì dúró'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGrandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Sibẹ laisko re ni ijọba apapọ gba lati maa san N30,000 gẹgẹ bii owo ọya oṣiṣẹ to kere julọ ni NaijiriaBuhari ti buwọ́lu #30,000 owó oṣù òsìsẹ́ .

Minista fun eto ẹ̀kọ́: Adamu Adamu

Awọn eeyan ko fi bẹẹ sọrọ nipa minista yii pupọ ni eyi ti awọn kan gba pe ko fi daa tó.

Awon mii ni ko ṣiṣẹ to lori eto ẹkọ ni ko jẹ kawọn eniyan mọ Ọjọgbọn yii bii minista to lagbara.

Image copyright @NGF
Àkọlé àwòrán Adamu ṣalaye pataki radio Fulfulde pe kawọn darandaran le ni ẹkọ to peye ni

Nibi ipade asegbẹyin awọn minista yii ni Adamu ti ni inu oun ko dun to nitori oun ko ri awọn ọmọ ko pe lọ sile iwe de idaji.

Oun ati Ngige, to jẹ minista igbode iṣẹ ni wọn jọ winá iyanṣẹlodi awọn olukọ Fasiti, ASUU fun odindin oṣu mẹta.

Isaac Adewọle: Minsita fun eto ilera

Image copyright @Isaac Adewole
Àkọlé àwòrán Iyanṣẹlodi ti pọ ju lasiko iṣejọba yii

Koko ọrọ ti awon eniyan fi binu si minista fun eto ilera julọ lori ayelujara ni nigba ti o ni: kii ṣe gbogbo oniṣegun oyinbo lo maa fi ṣe iṣẹ ṣe, awọn mii a lọ ṣiṣẹ agbẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn aláìsàn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ JOHESU

Ọpọlopo lo bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ọrọ ọjọgbọn to ti tukọ fasiti Ibadan nibi ti sanmọnti gbe dunlẹ fun ọpọlọpọ ọdun ko tẹ jẹ minista yii.Awọn ipinlẹ kan fara kaasa arun iba

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Iyanṣẹlodi Òsìsẹ́ ìlera fẹ́ náa tán bíi owó pẹ̀lú ìjọba ni oriṣii ẹka eto ilera Naijira pọ pupọ lasiko iṣejọba rẹ gẹgẹ bii minista ni NaijiriaJohesu sẹ́wé lé ìyanṣẹ́lódì.

Opọ awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun lo sa kuro ni Naijiria lọ si UK, Canada àti Saudi.Dokita ọmọ Naijiria jàjàbọ́ nílẹ̀ Ọba

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulrafiu Adeniji sọrọ lori isorogun Dokita ati osìsẹ́ ilera

Koko miran ti awọn eeyan tun fi n tasi minista yii lori ayelujara ni pé Aarẹ Buhari lọ si London fun ọpọlọpọ ọsẹ fun itọju ni eyi ti o fihan pe eto ilera Naijiria ko ti i goke agab tó.

Wọn ni ṣebi Buhari n polongo pe ko si irinajo lọ silẹ okeere fun itọju mọ ti oun ba wọle nitori pe wọn a tun eto ilera Naijiria ṣe

Kemi Adeosun: Minista fun eto iṣuna

Image copyright @Kemi
Àkọlé àwòrán O wu mi lati ṣiṣẹ fun Naijiria

A ko le ṣai menuba ọrọ Kemi Adeosun to jẹ minista fun eto iṣuna Naijiria tẹlẹ.'A sinmi ìwádìí lóri Kemi Adeosun'

Ọrọ aini ojulowo iwe ẹri NYSC ní Adeosun kòwé ransẹ́ láti gbààyè pe o sin ilẹ̀ baba rẹ nipa agunbanirọ lo jẹ ki o kọwe fipo silẹ.Itse Sagay wọ gàu lórí ọ̀rọ̀ Adeosun

Bi o ṣe kọwe fipo silẹ ni ọpọ gboriyin fun un pe o ṣe ohun to yẹ lori ayelujara nigba ti awọn miran tabuku ijọba Buhari ti wọn ni wọn n gbogun tiwa ibajẹ jẹgudu jẹra ni Naijiria.

Kemi Adeosun ni iroyin ni ko si ni Naijiria mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'