South Africa: Èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí fidio ti Aisha Buhari fi síta

Aisha Buhari si aarẹ South Africa
Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari si aarẹ South Africa

Ọrọ̀ n bọ́rọ̀ bọ... ni owe awọn agba n wi ati pe lowe lowe ni a n lu ìlù ogidigbo.

Ọkan lara awọn aṣofin ni orilẹ-ede South Africa, Julius Malema lo sọju abẹ niko ninu imọran to fun Aarẹ Ramaphosa ti wọn ṣẹṣẹ tun yan ni South Africa.

Malema gba Ramaphosa niyanju pe ko kọ̀ lati gbọran sawọn alagabagebe, arijẹ-nidi-madaru lẹnu.

Àkọlé fídíò,

Ìdílé tó gba olùkọ́ èdè Yorùbá fún àwọn ọmọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

O ni wọn kan ma maa tan aarẹ ni ṣugbọn wọn ko ni maa so ootọ ọrọ to nilo lati maa gbọ loorekoore fun idagbasoke ilẹ̀ South Africa.

Fọnran fidio ti Malema fi gbamọran yii ni Ayisha Buhari, iyawo aarẹ Mohammadu Buhari ti a ṣẹṣẹ dibo yan lẹẹkeji ni Naijiria naa fi soju opo twitter rẹ.

Kini àwọn eniyan Naijiria n sọ nipa Fọnra ti Aisha fi sita naa:

Ọpọlọpọ àwọn eniyan ni wọn ti n sọ oriṣiiriṣii nipa fọnran fidio naa lori ayelujara. Awọn kan n gboriyin fun aya aarẹ pé akin obinrin to n soju abẹ niko ni.

Ariṣe ni arika, arika ni baba iregun ni ero awọn mii pe aya aarẹ ti lo iru ọgbọn arekereke yii sẹyin lati fi ri ohun to n fẹ ni, ati pe ina èṣìṣì kii jo ni lẹẹmeji.

Àkọlé fídíò,

Ikorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Àkọlé fídíò,

'Nígbà tí mò ń wà Awolowo, Gowon, Babangida, mo fi ara mi sípo ọ̀wọ̀ tóri ...'

Awọn miran gba pé ohun ti aya aarẹ fẹ jẹ ni o n fọgbọn wa pe

Bẹẹ lawọn mii ni ṣebi aṣọ to kangun si egun ni wọn n pè ni jẹ̀pẹ̀, niṣe lo yẹ ki Aisha ba ọkọ rẹ sọ ododo ọrọ ninu iyara ko le gbọran daadaa

Àkọlé fídíò,

Jiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Loju àwọn ọmọ Naijiria omiran, aarẹ Buhari ti n kuna lati gbọ oo) tọ nkan to n ṣẹlẹ nitori pe awọn alatẹnujẹ kan ti rọgba yi aarẹ ka. Won gba aya aarẹ nimọran lati ba aarẹ Buhari sọ ootọ ọrọ.

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ọpọlọpọ lo n gboṣuba fun Malema pé o sọ ohun to jẹ awokọṣẹ fun gbogbo olori orilẹ-ede agbaye pe:

Àkọlé àwòrán,

Aisha, iwọ naa kọkọ lọ ba ọkọ rẹ sọrọ niyara kẹta!

Tọmaasi alaigbagbọ ni oye awọn miran lori ayelujara, wọn ko gbagbọ pe aya aarẹ funra rẹ gan an lo fi fidio naa sori ayelujara

Ohun kan ṣoṣo to hande ni pe, ọlọgbọn lo n jo ìlù agidigbo, ọmọran lo si n mọọ, asiko ti to fun awọn olori kaakiri agbaye lati dẹkun fifi awọn opurọ alatẹnujẹ yi ara wọn ka ki wọn gbe igbesẹ lati maa mọ okodoro ohun ti ara ilu to jade ninu ojo ati ninu oorun wa dibo yan awọn sipo n fẹ ni tootọ ki idagbasoke to yẹ le wa ni alaafia.

Awọn mii ni ki Buhari kẹkọ lara bi aarẹ Ramaphosa ṣe dahun si imọran Malema.

Àkọlé fídíò,

Footballers: ìkà láwọn aṣojú agbábọ̀ọ̀lù míì lágbàyé