2019 Guber Polls: Ẹ wo àwọn baba ìsàlẹ̀ òṣèlú tí wọ́n bá ìtìjú bọ̀ nínú ìbò gómìnà

Ibikunle Amosun ati Dapo Abiodun Image copyright Facebook/Ibikunle Amosun
Àkọlé àwòrán Idibo gomina ipinlẹ Ogun

Baba isalẹ ni itumọ oriṣirisi si awọn eeyan lorilẹede Naijiria. Ninu oṣelu Naijiria, baba isalẹ jẹ ẹnikan to lagbara lati rii wi pe oun funra rẹ wọle ibo tabi ẹni to ba ṣatilẹyin fun wọ le.

Ninu idibo gbogbogbo ọdun 2019 papaa julọ idibo gomina, ọpọ ninu awọn baba isalẹ oloṣelu lo gbere itiju.

Eyi ni diẹ lara awọn baba isalẹ oloṣelu ti nnkan ko ṣẹnu 're fun ninu idibo gomina to waye ni Naijiria lọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Abiola Ajimobi

Bi o tilẹ jẹ wi pe Gomina Abiola Ajimobi ni gomina akọkọ ti yoo wọle lẹẹmeji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo, o kuna lati wọ le ibo sile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.

Image copyright Facebook/Abiola Ajimobi
Àkọlé àwòrán Idibo Ipinlẹ Oyo

Ọgbẹni Kola Balogun ti ẹgbẹ PDP lo wọ le dipo Ajimobi fun Ẹkun Gusu Ipinlẹ Oyo.

Ko wa tan sibẹ o, Adebayo Adelabu to jẹ oludije si ipo gomina fẹgbẹ osẹlu APC naa tun fidi rẹmi lẹyin ti Ṣeyin Makinde ti ẹgbẹ PDP wọ le ibo ọhun.

Bukola Saraki

Sẹnẹtọ Bukola Saraki to jẹ Adari ile igbimo aṣofin agba l'Abuja kọkọ fidi rẹmi ninu ibo lati pada sile aṣofin agba mi olu olu orilẹede Naijiria.

Image copyright Facebook/Bukola Saraki
Àkọlé àwòrán Ibo gomina ipinlẹ Kwara

Bi iya nla ba gbe ni san lẹ, kekere a gori ẹni, Abdulrazaq Atunwa, oludije fẹgbẹ PDP ti Saraki tun ṣatilẹyin fun ninu ibo gomina ipinlẹ Kwara tun fidi rẹmi.

Abdulrahman Abdulrasaq ti ẹgbẹ APC la Atunwa mọ lẹ ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa.

Ariwo ''O TO GẸ'' ni ọpọ eeyan n pa nipinlẹ Kwara eyi to tumọ si pe awọn ko ni dibo fun Saraki ati ẹnikẹni to ba fa silẹ mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ibikunle Amosun

Lootọ ni Gomina Ipinlẹ Ogun Ibikunle Amosun jawe olubori ninu ibo ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, ṣugbọn o ni ijakulẹ ninu ibo gomina lẹyin ti Adekunle Akinlade oludije ẹgbẹ APM to ṣatilẹyin fun fidi rẹmi.

Ogun: Amosun, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fẹ́ forígbárí l'Ógùn

‘Gómìnà Amosun kò fẹ́ràn àwọn ará Ìjẹ̀bú’

Image copyright Facebook/Ibikunle Amosun
Àkọlé àwòrán Idibo gomina ipinlẹ Ogun

Loṣu kejila ọdun 2018 ni Gomina Amosun pinu pe oun ko ni gbaruku ti oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Dapo Abiodun.

Eleyi lo jẹ ko ṣatilẹyin fun Akinlade, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju rẹ ja si lẹyin ti Dapo Abiodun fẹyin Akinlade gbo lẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Rochas Okorocha

Gẹgẹ bi Gomina Ibikunle Amosun ṣe ṣatilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu miran fun ipo gomina nipinlẹ Ogun, bẹẹ naa ni Gomina Rochas Okorocha naa ṣe nipinlẹ Imo.

Gbogbo igbiyanju Okorocha lati rii pe ana rẹ, Uche Nwosu oludigbe ẹgbẹ oṣelu Action Alliance(AA) ni yoo gba ijọba lọwọ rẹ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Imo, pabo lo ja si.

Image copyright Rochas Okorocha
Àkọlé àwòrán Ibo gomina ipinlẹ Imo

Emeka Ihedioha oludije ẹgbẹ PDP lo jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Imo.