Kannywood: A ó fòfín dé eré ìfẹ ṣíṣe fún ọdun díẹ̀

Awon osere Image copyright Kannywood
Àkọlé àwòrán A ó fòfín dé eré ìfẹ ṣíṣe ni Kannywood fún ọdun díẹ̀

Kannywood tó jẹ ẹka àwọn oní fiìmù ní ilẹ̀ Hausa lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà tí bẹ̀rẹ̀ ètò láti fòfinde síṣe eré àgbélé wò fún títà fún ọdún díẹ̀ lánà àti taná wó àwọn ìhà ibomíràn.

Òfin tuntun yìí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní múlẹ̀ láti inú oṣù kẹ́fa gẹ́gẹ́ bi àlága ẹgbẹ́ àwọn óní fíìmù ní ìpínlẹ̀ Kano ti a mọ si Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (MOPPAN) ọgbẹni Kabiru Maikaba tó bá BBC sọ̀rọ̀ ṣe sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Maikaba fí kún-un pé fún ìgbà díẹ̀ báyìí, fíìmù àgbẹ́léwò eléré ìfẹ́ ló kó ìdá ọgọ́rin nínú ìdá ọgọ̀ru fíìmù tó ń jáde ní Aréwà, ṣùgbọ́n èyí kò yẹ ko ri bẹ́ẹ̀.

Image copyright Kannywood
Àkọlé àwòrán Alága ẹgbẹ́ àwọn óní fíìmù ní ìpínlẹ̀ Kano ti a mọ si Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (MOPPAN) ọgbẹni Kabiru Maikaba

"kílódé to jẹ pe fíìimù ìfẹ́ ni wọn a máa ṣe, ni ìgbà tó yẹ kí wọn móju tó àwọn àgbègbè tó kù. Ìhà Arewa ní àwọn ìtàn to làmìlaka pẹ̀lú àwọn ènìyàn to tí ṣe orire, gbogbo àwọn ǹkan wọnyii ló yẹ ki a kọ ibi ara sí"

"Nítori náà ni aṣe sọ pé láìpẹ́ yìí ti a ba ti pari ìdìbò ẹgbẹ́, a ti pinu lati máa wo ìwé ere ti àwọn ènìyàn ba kọ, èyí to ba ti jẹ mọ èrè ìfẹ́ ni a ó kó ni gbàá láye lati di ṣíṣe titi ti à ó fi ríì dáju pe àwọn ìhà toku náà ri amoju to"

Image copyright KAnnywood
Àkọlé àwòrán Onijo ni Ali Ali

Ìgbẹ́sẹ̀ yìí kìí ṣe ǹkan to dùn mo awọn kan nínú, Ali Ali tó jẹ ọ̀kan lára àwọn to máa n kọ àwọn ènìyàn ní ijo ni kannywood sọ pé àbá ti wọn ń da ọhun ko le múlẹ̀ rára àyà fi ti wọn ó ba pa Kannywood run pátápáta.

" Kò si fíìmù ti àwọn ènìyàn fẹ́ràn tó fíìmù ì fẹ́, ọ̀nà wo ni ẹ fẹ gba láti fi òfin de? Afi ti ẹka yìí ko ba ni si mọ. Mo gba pé ó ye kí àwọn to n kọ fiimu ó moju to ẹka míràn, sùgban ki wọn maa ṣe eré ìfẹ́ rárá, kò le siṣẹ́ rárá.

Image copyright Kannywood
Àkọlé àwòrán Ibi ere Makanta Biyu to jẹ ere ikfe ti Kannywood ṣe ti BBC si gbe e

Lóri bóyá fífòfinde ere ìfẹ yóò sọ àwọn kan di ẹdun arinlẹ gẹ́gk bi olori akoni nijo Ali ni ni ere ìfẹ ni o pọ̀ ti oun maa n ṣe nítori nínú eré ìfẹ́ ni orin àti ijo ti maa n waye.

"Mí ò rò pe èyí le ṣe akoba kankan fún mi nítori mi o gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn fofinde eré ifé ni Kannywood"

Image copyright Kannywood
Àkọlé àwòrán Ogun ọdún ni Ali Nuhu ti lò gẹ́gẹ́ bi òṣèrè ni Kannywood

Nínú ìfọ̀rọ̀wanilẹ́nu wò ti BBC ṣe pẹ̀lú gbájúgbaja oṣèré Kannywood Ali Nuhu lọ́dun to kọja, sọ pe ìdí ti Kannywood ṣe máa ń ṣe ere ifẹ ni pé, òhun lo n ṣe àfihan àwọn ènìyàn, Awọn Hausa dágbà nínú wíwo eré àgbéléwò India, ti gbogbo ènìyàn si mọ pe inú rẹ ni eré ìfẹ́ ti bẹ̀rẹ̀.

Nuhu to ni ile iṣe to n gbe fiimu jáde FKD yóò ṣe àgbéjade fiimu tó ṣẹṣẹ ṣe ti àkọlé rẹ̀ jẹ 'Ki yarda da ni' tósi jẹ fíìmù ìfẹ́ lósù tó n bọ, èyí ni Maikaba ń pinu láti fofinde.