NBC fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Fulani Radio

Awọn ara Ariwa Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori Fulani radio

Ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ lorilede Naijiria, NBC ti fun 'pe si gbogbo ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ lati yago fun ọrọ to le ṣakoba fun irẹpọ ati iduroṣinṣin Naijiria.

Eyi waye gẹgẹ bi esi si gbọyii sọyii to n waye laarin awn ile iṣẹ iroyin lori iwe aṣẹ "maa ṣiṣẹ" lati bẹrẹ ile iṣẹ rẹdio Fulani fun anfani ati le maa kọ awọn Fulani lẹkọọ.

Fun idi eyi, ajọ NBC rọ awọn ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ lati jẹ akọṣẹmọṣẹ ki wn si tẹle ilana ajọ naa ni gbogbo igba nitori ojuṣe wọn ni lati mu ilsiwaju ba ibagbepọ alafia lorilẹede Naijiria nipa igbohunsafẹfẹ.

Image copyright NBC
Àkọlé àwòrán NBC

Wọn ni ajọ to n bojuto ikẹkọọ awọn Fulani lorilẹede Naijiria kọwe bo ṣe tọ lati gba iwe aṣẹ igbohunsafẹfẹ fun ilọsiwaju ipolongo ikẹkọọ to fi mọ lori afẹfẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌdílé tó gba olùkọ́ èdè Yorùbá fún àwọn ọmọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Alakalẹ inu lẹta naa ni pe awn eto ori rẹdio naa yoo jẹ eyi to n kọ ni lẹkọ pọnbele ti wọn si ṣeto rẹ fun awọn arinrinajo bii apẹja, daran daran, ọdẹ, agbẹ ati bi iru rẹ.

Ẹwẹ, iroyin to wa n ja kalẹ ni wi pe ile iṣẹ rẹdio yii kan wa fun ẹgbẹ kan ni.

Ajọ NBC jẹ ko di mimọ pe iru iwe aṣẹ yii kan naa ni wn ti fun awọn ile ẹkọ giga atawọn ile iṣẹ ijọba mii lati maa gbohun safẹfẹ eyi to da lori ohun ti wọn nilo rẹ fun.