Children's Day: Àwọn ọmọdé tó ń ṣe bẹbẹ láwùjọ Afíríkà

SEkina àti Muiz
Àkọlé àwòrán,

Òun ní ẹni tó kr jùlọ tó sì gba àmì ẹ̀yẹ ní òrílẹ̀-èdè GhanaChildren's Day: Àwọn ọmọde tó ti bẹ́bẹ́ láwùjọ Afíríkà

Òní ni àyájọ ọjọ́ àwọn èwé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń ri sí ẹ̀tọ́ ọmọ wẹ́wẹ́ lágbàyé (UNICEF) ṣe là á kalẹ̀.

Gbogbo ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn ún, ọdọọdún ni ó máa ń wáye, ṣùgbọ́n ní ọ̀dún yìí àjọ náà pé àkọlé rẹ̀ ní "Gbogbo ọmọ ló ní ẹ̀tọ́"

Àjọ UNICEF ní pé bó tilẹ̀ jẹ pé àwọn ò sinmi, sùgbọ́n àwọn ọmọde ní Nàìjíríà kò sì tii ní ẹ̀tọ́ sí ètò ìlera, oúnjẹ, ètò ẹ̀kọ́ àtí àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn.

Àkọlé fídíò,

Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ

Lọdun 2019 yìí, UNICEF ṣe àfilọ́lẹ̀ ìwé pélébé ti wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ni "Passport to Your Right" tí yóò wà ni èdè Hausa, Igbo àti Yorùbá pẹ̀lú ìléri pé ọmọ kọ̀ọ̀kan yóò ni ẹ̀tọ́ sii ni ọdún 2030. láti ṣe àyájọ́ ọjọ́ ọmọ wẹ́wẹ́.

Àkọlé fídíò,

Ẹ wo àrà àwọn ọmọ kékeré ń fi ẹ̀kọ́ kọ̀mpútà dá

Àwọn ti ìlé iṣẹ́ BBC Yorùbá n gbe yẹwo fi sami ayẹyẹ ọmọ wẹ́wẹ́ t'orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tí làmìlaaka nínú ǹkan ti wọ́n yàn láàyò lagbaye ni:

Jeremaiah Owura Addo (GHANA)

Àkọlé fídíò,

Jeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Ọmọ yìí gan an ni à bá sọ pé orí rẹ̀ pé bii ti alájọ Ṣomolu.

Ọmọ ọdún mejì yìí kò dé iléèwé rí, àmọ́ ó mọ olú ìlú orílẹ̀-èdè ogójì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mii tó wà láyé.

Àwọn ènìyàn tilẹ̀ ni òun ló yẹ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ ọmọ tó jáfáfá jù lọ lágbàyé.

Ṣekinat Quardir(NAIJIRIA)

Àkọlé àwòrán,

Sekinat Quadri

Ọmọdébìnrin yìí Sekinat Quadri jẹ́ kí àwọn òbí rẹ̀ mọ́ pé abẹ̀sẹ́kùbíòjò ló wu òun, wọ́n sì ń tíì lẹ́yìn.

BBC Yorùbá bá ọmọdébìnrin náà tó fẹ́ dà bí Anthony Joshua, lálejò, ó kọjá àfẹnusọ.

Àkọlé fídíò,

Sekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua

DJ Switch (GHANA)

Àkọlé àwòrán,

Children's Day: Àwọn ọmọde tó ti bẹ́bẹ́ láwùjọ Afíríkà

Ọmọdébìnrin, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀wá tó jẹ́ apo orin tàkasufe pọ yìí 'DJ switch' ní àṣírí márùn-ún fún ẹnì tó bá fẹ́ dà bíi rẹ.

Àkọlé fídíò,

Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Òun ní ẹni tó kéré jù lọ tó sì gba àmì ẹ̀yẹ ní òrílẹ̀-èdè Ghana Children's Day: Àwọn ọmọde tó ti bẹ́bẹ́ láwùjọ Afíríkà

Demilade Adepegba( NAIJIRIA)

Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni Damilola Adepegba, tó ń fi fèrè dá bí ẹdun, rọ̀ bí òwè!

Demilade nínú fídíò yìí sọ fún BBC Yorùbá pé gbogbo ìgbà tí òun bá ń fọn fèrè ni inú òun máa ń dùn.

Ìkorodu Boiz (NAIJIRIA)

Àkọlé fídíò,

Ikorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

Ǹkan ti àwọn ọmọ wọ̀nyìí yàn láàyò ni láti maa sín àwọn olókìkí ènìyàn jẹ, Muiz Sanni (14), Fawas Sanni (10) àti Malik Sanni (8) jẹ́ ọmọ ìyá kan náà ti wọ́n sì máa ń dẹ́rin pa àwọn ènìyàn.

Joshua Robert Poshjosh (NAIJIRIA)

Àkọlé fídíò,

Josh Posh: Inú mi máa ń dùn láti kọrin fún àbúrò mi ní kékeré

Joshua Robert (Poshjosh) jẹ ọmọ bíbí Nàìjíríà tí a bí sí òkè òkun.

Obí rẹ̀ gbìyànjú láti fí èdè àti àṣà kọ́ ọ tó si dí ohun àmúyangan láàrin àwọn òyìnbó lókè òkún.

Ohun to máa n mú inú rẹ̀ dùn jùlọ ni pé, ó fẹ̀ràn láti máa kọrin fún àbúrò rẹ̀.

Oluwapamilerin Mihael Ayanlere (NAIJIRIA)

Àkọlé fídíò,

Àyàn: Ti mo bá ti gbọ́ ohùn ìlù ni àárẹ́ mi ma ń lọ!

Kékere àkin ní Oluwapamilerin, ọmọ ọdún mọ́kànlá to yan ìṣẹ́ bàbá rẹ̀ láàyò láti kekere, bó se ń lu omele, gángan, ìyá ìlù, bákàn náà lo n lu àpapọ̀ ìlù ìgbàlódé tí wọ́n ń pe ni (Drum Set).

Àkọlé fídíò,

'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

Kareem Waris (NAIJIRIA)

Àkọlé fídíò,

Waris Kareem: Emmanuel Macron kan sáárá lórí àwòrán tó yà

Gbájúgbaja ayàwòrán yìí di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà ti ààrẹ orílẹ̀èdè Faranse, Emmanuel Macron ti gbé oríyìn fún un.

Ọmọkùnrin, ọmọ ọdún mọ́kànlá náà, nígbà tó ya àwórán ààrẹ náà láàrin wákàti méjì tó sì gbé e fún un ní Africa Shrine.

Láti ìgbà yìí ni ọmọ náà tí di ènìyàn ǹlá tí iṣẹ́ ọwọ rẹ̀ si ti dí èyí ti wọ́n ń rà káàkírí.