'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bolanle Sarumi Aliyu: Nígbà tó bá di àsìkò tèmi, èmi náà á dé 'bẹ̀

Àwọn 'agent' mi ló fọ́mbù lọ́jọ ìbò nitori owó -Sarumi

Arabinrin Omobolanle Sarumi Aliyu ni obinrin akọkọ to jade lati dije dupo gomina ipinlẹ Ọyọ.

A bii ni ọjọ kejilelogun, oṣù kẹta, ọdún 1979. Ọmọ ilẹ Gẹẹsi ni Iya rẹ, baba rẹ Ali Balógun Sarumi si jẹ ọmọ ile Oluyọle.

Bi ẹ ba ranti lasiko ipade itagbangba BBC Yoruba pẹlu awọn oludije gomina ni ipinlẹ Oyo, Bolanle Sarumi ni gbogbo awon ọmọ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju marun un lọ yoo gba eto ilera ofe.

Bakan naa ni awon arugbo ti ọjọ ori wọn ko din ni odun marundinlaadota yoo maa janfani eto ilera ọfẹ bi oun ba wọlé.

Sarumi ṣalaye fun BBC Yoruba idi ti oun ṣe darapọ mo ẹgbẹ oṣelu PDP bayii.

O ni iru awọn ọna ti ko tọ ti awọn kan n lo lati kowo jẹ ko ni ṣi silẹ ni ijọba oun. Fun apẹrẹ, "ko ni si ọfiisi ọkọ gomina ninu iṣejọba temi".

Lori ọrọ abo, Sarumi ni aisi olori gidi ni kii mu ki ilu toro.

O ni ko lee si abo laisi iṣẹ. O ni oun yoo ro awọn ọdọ lagbara.

Bolanle Sarumi Aliyu sọ fun BBC Yoruba pé mọkan-mọkan loye n kàn, nígbà tó bá di àsìkò tèmi, èmi náà á dé 'bẹ̀.

O mẹnuba awọn ipenija to koju ṣaaju idibo gẹgẹ bii obinrin to n dije dupo nipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ tuntun.

Ni ipari, o sọrọ lori ipinnu rẹ lati tẹsiwaju ninu oṣelu nitori pe o wa ninu súrà oun lati tukọ̀ ipinlẹ Oyo lọjọ iwaju.