Rain: Ìgbà òjò léwu, ohun tó o ní láti mọ̀ rèé

Agbara ojo ni orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Pulse

Ni ọdọọdun ni agbara ojo maa n gbẹmi ara ilu ni orilẹ-ede Naijiria.

Eyi lo jẹ ki ọrọ ọpọ ẹ̀mí àti dukia sọnu ni Naijiria.

Onimọ nipa ọrọ aabo ayika kan, Ọgbẹni Ehi Iden sọ fun BBC wi pe, ọrọ agbara ojo lagbara ju bi awọn eniyan ṣe ro o lọ.

Àkọlé fídíò,

Omiyalé Àkútè: N50 si N100 làwọn èèyàn fi ń kọjá lórí ẹ̀kún omi l‘Ákútè

Awọn ìgbésẹ tí Ehi ni o le doola ara ilu nigba ojo ree:

1. Mọ bi ọna adugbo rẹ ṣe ri daradara loju mọmọ:

Iden ni ki o to le yago fun ijamba ti agbara ojo ba ka ọ mọ adugbo rẹ, o ni lati mọ bi ọna adugbo rẹ ṣe ri daju.

Eyi ni yo lè jẹ ki ọ mọ ibi ti oju gọ́tà tabi ihò wà láti yago fun.

Àkọlé fídíò,

Afeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Onimọ naa ni, fun apẹẹrẹ, bi agbara ojo ṣe n ṣọsẹ ni adugbo kọọkan ni Ipinlẹ Eko lagbara ju'ra wọn lọ.

Ehi ni ọpọlọpọ awọn iho ti oloyinbo n pe ni 'manhole' pọ̀ ni oju popo Ipinlẹ Eko to jẹ ewu fun awọn eniyan ni ọsan lai tii sọ iru ewu ti wọn jẹ fun ara ilu ni alẹ tabi nigba ti ojo ba rọ.

Oríṣun àwòrán, Stelladimokorkus

Àkọlé àwòrán,

Eyi ni yo lè jẹ ki ọ mọ ibi ti oju gọ́tà tabi ihò wà láti yago fun.

2. Agbara ojo kii ṣe oun afojudi rara:

Awọn onimọ ni agbara ojo to ga to iwọn bata ẹsẹ kan le wọ ọkọ lọ loju popo.

Idi ree ti wọn fi gba awọn awakọ ni iyanju lati ri wi pe wọn ko gbe ọkọ sita nigba ti agbara ojo ba wa lori popo.

Àkọlé fídíò,

'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

Fun awọn ti agbara ojo naa ba ka mọ irinajo, ni wọn ni ki wọn yẹra fun ijamba, wọn ni lati wa ọna lati wa ọkọ wọn sibi kan, ki wọn si jade ninu rẹ ni kiakia.

Ijọba gbọdọ gbé igbimọ alaabo kalẹ laarin awọn olugbe awọn adugbo ti agbara ojo ti maa n ṣọsẹ.

Oríṣun àwòrán, Pulse

Àkọlé àwòrán,

Ijọba gbọdọ gbé igbimọ alaabo kalẹ laarin awọn olugbe awọn adugbo ti agbara ojo ti maa n ṣọsẹ.

3. Imọran deede nipa agbara ojo:

Ehi ni ọpọlọpọ igba ni iroyin ti fi han bi awọn ọmọ ile iwe ṣe ba agbara ojo lọ nigba ti wọn ba n bọ nile iwe.

O ni idi ti iru eyi fi n ṣẹlẹ ni wi pe, awọn obi ko ni imọran to to lori ewu to wa ninu ki awọn ọmọ wọn jade nigba ti agbara ojo ba wa lori popo.

O ṣalaye pe, ko si oṣiṣẹ kankan to yẹ ko padanu ẹmi rẹ nitori wi pe ko fẹ pẹ de ibi iṣẹ ni ọjọ ti ojo ba rọ.

Idi ree to fi sọ wi pe ẹrọ rẹdio lo yẹ ki ijọba fi maa polongo imọran nipa bi awọn eniyan ṣe le ṣọra lasiko ojo.

Oríṣun àwòrán, TVC

Àkọlé àwòrán,

Ehi Iden ni ko si oṣiṣẹ kankan to yẹ ko padanu ẹmi rẹ nitori wipe ko fẹ pẹ de ibi iṣẹ ni ọjọ ti ojo ba rọ.

Awọn ijamba agbara ojo to ti ṣẹlẹ sẹyin

Ni ọdun 2011, o to ọgọrun un eniyan ti ajọ Red Cross ni o padanu ẹmi wọn ninu agbara ojo ni ilu Ibadan.

Yatọ si awọn to gbẹmi mi, ọpọlọpọ ni o padanu dukia ati awọn ọrọ aje wọn.

Ni oṣu keje, ọdun to tẹlee, 2012, o din diẹ ni irinwo eniyan ti omiyale ati agbara ojo pa kaakiri orilẹ-ede Naijira, ni paapaa, Ipinlẹ Eko nibi ti ọpọlọpọ eniyan ti ku.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, NEMA sọ nigba naa wi pe o le ni miliọnu meji ọmọ Naijiria ti agbara ojo sọ di alainile lori nigba naa.

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun