Ta ló ga jù lábà? Agùntáṣọlò Afeez ni o!
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Afeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Gígùn ti mo gùn ti gbé mi dé America rí -Afeez.

A ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, BBC ba Afeez Oladimeji Agoro to jẹ Aguntaṣọlọ ọkunrin sọrọ lori bo ṣe jẹ akanda.

Afeez ṣalaye fun Akoroyin Ayaworan BBC, Joshua Akinyemi pe gigun ti oun gun ju awọn eniyan lọ yii ti fun oun ni anfaani lati lọ silẹ okeere bii Amerika.

Afeez sọrọ lori àwọn idojukọ ti oju rẹ n ri lori gigun to gun yii bii ki o ṣalai ri aṣọ to maa gbaa lọja tabi ki o di àpéwò fun awọn eniyan nigba ti wọn ba kọkọ foju kan an.

Afeez ga ni iwọn ẹsẹ bata to din diẹ ni mẹjọ bẹẹ ko sanra pupọ.

Aguntaṣọọlo Afeez gba awọn obi nimọran lati ma gbe ọmọ wọn lọ fun ayẹwo nile iwosan ti wọn ba ti kẹ́fín ohunkohun ti ko ri bo ṣe yẹ lara rẹ.