Children's Day: Èwe ni ọjọ́ ìwájú ìran ènìyàn-Adeyeye Enitan Ogunwusi

akẹkọọ
Àkọlé àwòrán,

Kabiesi Ojaja 11 sami ayẹyẹ ayajọ àwọn ewe pẹlu àrà

Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja II gbalejo awọn ewe kaakiri ile iwe ni Ile Ife ati agbegbe rẹ.

Loni ayajọ ọjọ awọn ewe kaakiri agbaye gẹgẹ bi UNICEF ṣe laa kalẹ naa ni Oba Ile Ifẹ darapọ mọ gbogbo òbí agbaye lati sami ayẹyẹ yii pẹlu awọn ọmọde.

Lasiko ti Kabiesi n gbalejo awọn ọmọ wọnyii lo fara balẹ ṣalaye itan Oodua àti ìtẹ́ ni aafin fawọn ogo wẹẹrẹ wọnyii.

Àkọlé àwòrán,

Tọkunrin-tobinrin lo yọ ayọ ayajọ awọn ewe tọdun 2019 laafin Ojaja 11 nile Ifẹ.

Àkọlé fídíò,

'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀ gbàlejò àwọn èwé sí ìdùnnú àwọn ọ̀dọ́ tilu tifọn ni ile Ifẹ.

Oba yii fidunnu rẹ han lori awọn ọmọde nipa bi bawọn kọrin ati jijo ijo ayọ laarin wọn.

Àkọlé àwòrán,

Tayotayo ni Kabiesi gbalejo awon ogo weere

Baba gbogbo ọmọ Oodua wure aṣeyọri fun gbogbo awọn ọmọ ti wọn wa sibi eto naa atawọn ti wọn ko le wa lapapọ.

Àkọlé fídíò,

Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

Kabiesi ni oju kii pọn iṣin ki ọmọ inu ẹ ma là, o di dandan ki ori awọn ogo wẹẹrẹ yii kan oke.

Ọọni gba pe, oriṣa ti a ko ba fidi ẹ han ọmọde kii pẹ parun, o yẹ kawọn ọmọ yii mọ pataki iran wọn.

Àkọlé àwòrán,

idije orisi lo sele to mu inu awon omode dun ni Ife

Lẹyin eyi ni awọn ọdọ yii ni oore-ọfẹ lati dije ninu ere idaraya loriṣirisi bii gbigba bọọlu ori tabili, kẹkẹ gigun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò,

Ọọni Ogunwusi Adeyẹye pe fun itọju awọn ọdọ

Ọpọlọpọ obi, alagbatọ ati awọn olukọ awọn akẹkọọ wọnyii ni wọn kọwọrin wa pẹlu awọn ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò,

Ooni: Mo ti fi ọ̀rọ̀ obinrin tó ń parọ́ ìfẹ́ mọ́ mi sun agbófinró

Gbogbo wọn pata ni Kabiesi wure ipese fun pe onikaluku a jere iṣẹ ati làálàá wọn lori awọn ọmọ yii.

Àkọlé àwòrán,

Tẹrin tọyaya tagbara n rin ko odo lọna lawọn ewe rin pade Oba Alayeluwa loni

Àkọlé fídíò,

Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Ọpọlọpọ idije Tan-mọọ lo waye nibi eto akanṣe fawọn ewe naa bii ti idije ìṣirò, ijo ibilẹ ati afihan aṣa Yoruba loriṣiiriṣii.

Opolopo ẹbun ni awọn ọmọ ko lọ sile pẹlu idunnu lẹyin ti wọn ti yan bi ologun tan fun Oba atawọn alejo to wa nibẹ.

Àkọlé àwòrán,

Opolopo ẹbun ni awọn ọmọ ko lọ sile pẹlu idunnu lẹyin ti wọn ti yan bi ologun tan fun Oba atawọn alejo to wa nibẹ.

Àwọn Olukọ paapaa fẹsẹ rajo ninu idije ti onikaluku rẹrin pẹlu idunnu ti awọn kan si gbegba oroke ninu idije naa.

Diẹ lara awọn to ṣajọyọ yii pẹlu Alayeluwa ni alaga awọn onimọ ẹrọ ẹka ti ipinlẹ Oyo / Osun / Ondo / Ekiti, Ogbẹni Kola Akosile atawọn mii.