Nigeria 2019 budget: Ààrẹ Muhammadu Buhari buwọ́lu owó ìṣúná ọdún 2019

Aarẹ Buhari Image copyright Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà buwọ́lu owó ìṣúná 2019

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu owo iṣuna ọdun 2019.

Lọjọ Aje ni Buhari buwọlu owo iṣuna naa to ku diẹ ko pe triliọnu mẹsan an Naira (8.92 trillion) eyi to ti sọ aba owo iṣuna naa di lilo bayii.

Amọ ṣa, Minisita fun eto iṣuna ati aato ilu, Udoma Udo-Udoma kede pe gbogbo akọsilẹ to wa ninu owo iṣuna ti aarẹ buwọlu ọhun yoo jẹ fifi si ita gbangba fun ara ilu nibi eto kan ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun.

Image copyright Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà buwọ́lu owó ìṣúná 2019

Lara awọn to peju sibi eto naa ni igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara, igbakeji olori ile aṣofin agba, Ike Ekweremadu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka