Kannywood Kidnapping: 'Mọ́ngòrò nìkan ni wọ́n fún mi jẹ ní àhámọ́ ajínigbé'

Salisu Mauazu Image copyright Salisu Muazu/Facebook
Àkọlé àwòrán Aworan akọkọ ti Muazu ya re e, lẹyin ti wọn tu u silẹ lọsan ọjọ Aiku

Gbaju-gbaja oludari ere Kannywood ti awọn ajinigbe tusilẹ lọjọ Abamẹta, Salisu Muazu ti sọ fun BBC pe mọngoro nikan ni awọn ajinigbe naa fun oun ati ọrẹ mẹta ti wọn jigbe jẹ fun ọjọ mẹta.

Oludari ere ọhun to n gbe niluu Jos lo n rinrinajo lọ si ipinlẹ Plateau lati Kaduna lọjọbọ to kọja pẹlu aburo rẹ, ati awọn ọrẹ nigba ti awọn ajinigbe naa da wọn lọna.

"Ile ti wọn fi wa si ko ni orule rara. Ori wa ni ojo n rọle, mọngoro nikan si ni wọn n ka fun wa jẹ lori igi kan to wa nitosi ibẹ fun ọjọ mẹta."

"Awọn ajinigbe naa sọ fun wa pe awọn yoo san owo ibọn AK47 ti awọn ya, owo ọga wọn lara miliọnu mẹwaa Naira ti a ba san."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Muazu ṣalaye pe awọn ajinigbe naa sọ fun awọn pe awọn kan to wa ni ipo pataki n lọwọ si awọn ijinigbe to n waye ni Naijiria.

Image copyright Salizu Muazu
Àkọlé àwòrán Salisu sọ pe mọngoro nikan ni awọn ajinigbe naa fun awọn jẹ f'ọjọ mẹta.

Muazu sọ pe gẹgẹ bi oludari ere, oun yoo lo iriri naa lati ṣe sinima ti yoo gba ami ẹyẹ fun oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Miliọnu mẹwaa Naira ni mọlẹbi Muazu san ki wọn o to tu wọn silẹ.

Ojoojumọ ni iroyin ijinigbe n jade lorilẹ-ede Naijria, botilẹjẹ pe ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa sọ laipẹ yii pe o ti dinku lẹyin ti awọn ọlọpaa so okun aa bo le lawọn opopona nla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'