Oyo NLC: A kò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láti d'ẹ́rù ba ìjọba tuntun

Ile ẹgbẹ NLCto wa nilu Ibadan
Àkọlé àwòrán Oyo NLC mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọyọ, NLC, ti so iyanṣẹlodi rẹ rọ.

Lasiko to n kede igbesẹ naa, Alaga ẹgbẹ NLC nipinlẹ Ọyọ, Comrade Bayọ Titilọla-Sodo, sọ pe awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi pẹlu ireti pe ọjọ diẹ to ku ninu iṣejọba to wa nita lọwọlọwọ nipinlẹ Ọyọ yoo so eso rere fun awọn oṣiṣẹ.

O ni kii ṣe ọna tabi erongba lati dẹru ba ijọba to n bọ.

Lara awọn ohun to fa a ti awọn oṣiṣẹ naa fi yanṣẹlodi gẹgẹ bi Titilọla-Sodo ṣe sọ ni ajẹsilẹ owo oṣu ati owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ fẹhinti, eyi toto ọgọta billiọnu Naira.

Bakan naa ni fifi opin si aṣẹ ti ko jẹ ki wọn o gbe awọn oṣiṣẹ lati ibikan si omii, gbigba awọn oṣiṣẹ ti wsn da duro lọna aitọ pada, ajẹsilẹ owo oṣu awọn olukọ ileewe alakọbẹrẹ ati awsn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

O wa kesi gomina tuntun fun ipinlẹ Ọyọ, Onimọ Erọ Seyi Makinde, pe ko ma ṣe yi ohùn pada lori awọn ileri to ṣe lasiko to n polongo ibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn kan ń dunú, àwọn kan ń ṣe ìkìlọ̀ lórí èsì ìdìbò ààrẹ

Ọjọ Ẹti to kọja ni ẹgbẹ oṣiṣẹ naa bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionContortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!