Buhari: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti ológun ti kùnà lórí ètò ààbò Nàìjíríà

Bukola Saraki, Muhammadu Buhari ati Yakubu Dogara Image copyright Presidency
Àkọlé àwòrán Ifọrọwerọ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari

Aarẹ orilẹede Naijiria Muhammadu Buhari sọ gbankọgbi ọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe lalẹ ọjọ Aje lori ẹrọ amohunmaworan ijọba apapọ, NTA.

Eyi ni koko marun un ninu awọn ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ ninu ifọrọwerọ naa.

Ọrọ lori eto iṣuna

Aarẹ Buahri sọ oko ọrọ si awọn adari ile aṣofin agba l'Abuja, Bukọla Saraki ati Yakubu Dogara, lori ọrọ eto iṣuna ọdun 2019. O ni wọn ko nifẹ orilẹede Naijiria l'ọkan.

Aarẹ ni ti Saraki ati Dogara ba ni ifẹ Naijiria lọkan, wọn ko ni gba ki aba iṣuna wa ni iwaju ile fun oṣu meje lai buwọ lu u.

''Baba go slow''

Aarẹ Buhari sọ ninu ọrọ rẹ tun fesi pada fun awọn to n pe ni ''baba slow'' pe, yoo rii gbangba ni saa keji oun, boya lootọ tabi irọ ni oun lọra ninu iṣejọba oun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ sọ pe Saraki ati Dogara ko ni ifẹ Naijiria lọkan, ni wọn ṣe mu idiwọ ba aba iṣuna fun oṣu meje.

Buhari ni oun yoo ya agbado haa si awọn to n pe oun ni ''baba go slow'' lẹnu ni saa keji yii.

Ọrọ eto aabo

Aarẹ Naijiria tun dẹbi eto aabo to mẹhẹ lorilẹede yii ru awọn ọlọpaa ti wọn ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.

Image copyright Nigeria Presidency

O ni kudiẹkudiẹ nileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ologun lati igba ti oun ti fiṣẹ ologun silẹ lo ṣe okunfa eto aabo ti ko mọyan lori ni Naijiria.

Buhari ni oun fẹ ki ẹka eto aabo ṣiṣẹ takuntakun sii, lati ri pe eto aabo duro daada l'orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Ọrọ lori awọn minisita

Lori ọrọ awọn minisita ti Aarẹ Buhari yoo yan fun saa keji ijọba rẹ, o ni oun ko tii sọ fun ẹnikan nipa wọn.

Aarẹ ni, o yẹ ki awọn eeyan ni igbẹkẹle ninu oun, nitori pe ko si ẹnikan to le tọka si ọkankan ninu awọn minisita to ba oun ṣiṣẹ pe wọn wuwa ibajẹ kan tabi omiiran lati ọdun mẹrin sẹyin.

Aarẹ ni oun ko le sọ bo ya awọn minisita kan yoo si di ipo wọn mu, tabi oun yoo dagbere fun awọn kan lara wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Ọrọ lori awọn gbajumọ ati ọmọwe

Aarẹ Buhari sọ pe ata akara ti ko ran ikọ ni ọrọ awọn gbajumọ ati ọmọwe to n tako ijọba oun jẹ.

Aarẹ ni awọn gbajumọ ati ọmọwe maa n tako ijọba oun, lati le gba iyi lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lasan ni.

Aarẹ tun sọ pe, oun yoo gbiyanju lati ri wi pe ile iṣẹ ọlọpaa ati ẹka eto idajọ gbopọn si ni saa keji ijọba oun.