Nollywood gba àlejò ọmọkùnrin jòjòló

Bidemi Kosoko nigba to wa ninu oyun Image copyright Bidemi Kosoko

Idunnu subu layọ ni lowurọ ọjọ Iṣẹgun nigba ti ariwo gba ilẹ kan pe gbajugbaja oṣere ori itage lobinrin kan, Abidemi Kosọkọ ti di iya ikoko.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni ọmọbinrin naa ṣe idana, to si lọ sile ọkọ.

Nigba to n kede pe oun ti ru re, ti oun si sọ re, Bidemi kede loju opo ikansira ẹni Instagram rẹ pe ọmọkunrin tuntun jojolo ni ọba oke fi ta oun lọrẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni kete ti iroyin naa si tan kalẹ, ni ọpọ awọn eeyan ti n ki ku oriire aruye yii.

Bidemi, tii baba rẹ naa jẹ gbajumọ oṣere tiata, Jide Kosokọ, naa fi tayọtayọ kede pe oluwaseun fun ẹbun ọmọ naa ti oun si bi layọ ati alaafia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Lara awọn osere tiata to ti ki Bidemi ku ayọ abara tintin la ti ri Antar Laniyan, Madam Sajẹ, Wumi Toriọla, Ronkẹ Oshodi Oke, Ọdunlade Adekọla ati bẹẹ bẹẹ lọ.