EFCC: Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin tó ń kọ́ iṣẹ́ Yahoo l‘Eko lọwọ́ EFCC tẹ̀

An afurasi akẹkọọ Yahoo ti ọwọ EFCC tẹ Image copyright EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ọdaran nidi owona lorilẹede Naijiria, EFCC, ti kede loju opo ikansira ẹni Facebook rẹ pe, ọwọ palaba oludasilẹ ileẹkọ kan ti wọn ti n kọ nipa iwa lilu jibiti lori ayelujara, taa mọ si Yahoo ti segi.

Atẹjade kan, ti agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Tony Orilade fisita lọjọ isẹgun lo sisọ loju ọrọ yii.

Atẹjade naa ni awọn osisẹ ajọ EFCC to wa nilu Eko, lo ya bo ileẹkọ naa, to wa ni ojule Kẹrinla, opopona Animasaun, ladugbo Ojodu-Berger nilu Eko, lasiko ti awọn akẹkọ ileẹkọ naa n gba idanilẹkọ lọwọ.

Lara awọn eeyan ti ọwọ awọn osisẹ ajọ EFCC naa tẹ ni ẹnikan ti wọn furasi bii oludasilẹ ileẹkọ naa, Frank Chinedu, tii se ẹni ọdun mejilelogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan yoku ni akẹkọ mẹjọ, ti wọn n gba idanilẹkọ lọwọ lasiko ti awn osisẹ EFCC wọ ileẹkọ Yahoo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Lara awọn ohun ti awọn osisẹ EFCC ka mọ awọn afurasi naa lọwọ ni ẹrọ ayarabiasa agbeletan mẹsan, foonu alagbeka mẹrindinlogun, pẹ́lu ọkọ Toyota Camry ti nọmba rẹ jẹ EPE 406FN.

Image copyright EFCC

Wayio, ajọ EFCC ti sọ agadagodo si ẹnu ọna ileẹkọ Yahoo naa, to si ti fi ọda pupa kọ akọle si ara ile naa pe ẹnikẹni ko gbọdọ sun mọ ibẹ.