Swearing in 2019: Seyi Makinde ní òun kò yan igun ẹgbẹ NURTW kankan nípọ̀sìn

Seyi Makinde Image copyright Seyi Makinde

Yoruba ni o n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de, amọ ni ti gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde, oju lo fẹ mu to.

Idi ree to fi n lọgun tantan tan pe, ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero kankan abi ẹnikẹni to ba gbero lati fa wahala lẹsẹ lasiko ayẹyẹ ibura oun sipo gomina, eyi ti yoo waye lọjọru, yoo jẹ iyan rẹ nisu.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Seyi Makinde, eyiun Ọmọọba Dọtun Oyelade fisita , lo sisọ loju ọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa tun n fi ewe ọmọ mọ igun ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW to ba gbero lati da omi alaafia ipinlẹ Ọyọ ru ki wọn to se ibura, lasiko ibura ati lẹyin rẹ, yoo ge ika abamọ jẹ.

Seyi Makinde ni ohun ti n hu gbọ pe awọn eeyan kan ti n leri leka lati da rogbodiyan silẹ lọjọru , to si n rọ an igun ẹgbẹ NURTW to n se asọ, lati so ewe gbejẹ mọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagosians: Eni tó ní owó ló ń kọ Will

Seyi Makinde wa fi ọwọ idaniloju sọya pe oun ko yan igun ẹgbẹ awakọero kankan nipọsin, nitori ko si ẹmi to kọja ofin,pẹlu afikun pe oun ti kesi ileesẹ ọlọpaa lati fi imu ẹnikẹni to ba sokunfa rogbodiyan danrin.

Seyi Makinde wa n mu da awọn araalu loju, to fi mọ awọn iyalọja, lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ̀, ti ijọba oun si ti pinnu lati jẹ ki eto aabo fẹsẹ rinlẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?