Democracy Day: Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ogun àti Kwara fún ìbúra gómìnà tuntun

Ẹ wo awọn aworan igbaradi fun iburawole ni awọn ipinlẹ:

Ipinlẹ Ọyọ:

N jẹ ẹ mọ pe gomina ti yoo se ibura lọjọru ni ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti kan si papa iṣere Obafemi Awolowo nibi ti ayẹyẹ ibura naa yoo ti waye.

Lasiko to si wa ni ibudo naa, lo se idanilẹkọ nipa bi eto igbaradi naa yoo se waye. Koda, o tun wọ inu ọkọ ti yoo gbe kaakiri wo .

Koda, Awọn ase ibudo lọṣọ atawọn ohun eelo ikọrin gan ti wa nikalẹ fun ayẹyẹ ibura naa.

Ibadan
Àkọlé àwòrán Igbaradi ni pẹrẹwu! Seyi Makinde n gbaradi fun ayẹyẹ ibura rẹ
Makinde n bọ awọn eeyan lọwọ ni ibudo ibura
Àkọlé àwòrán Awọn ara ipinlẹ Ọyọ ti ni gomina tuntun
Makinde gun ọkọ wo fun igbaradi ibura
Àkọlé àwòrán Makinde n yan fanda lori papa saaju ọjọ iburawọle
Awọn atibaba ti wọn ta si papa isere idaraya Obafemi Awolowo
Àkọlé àwòrán Papa isere idaraya Obafemi Awolowo gbe awọ tuntun wọ fun ayẹyẹ ibura Seyi Makinde
Awọn eeyan kan n ta atibaba
Àkọlé àwòrán Atibaba ree fun awọn alejo, o lee daboo bo awọn ero lọwọ ojo ati oorun
Awọn asọ iselesọ alaranbara ninu papa isere Obafemi Awolowo
Àkọlé àwòrán Papa isere Obafemi Awolowo ti yatọ gbaa fun ibura Seyi Makinde
Awọn apoti ti wọn to ẹru si
Àkọlé àwòrán Pẹpẹyẹ yoopọn ọmọ nibi ibura Seyi Makinde lọla. Kekere kọ

Ipinlẹ́ Ogun:

Gbogbo eto lo ti to bayii ni papa isere idaraya MKO Abiola nilu Abẹokuta fun ayẹyẹ ibura gomina ti ilu dibo yan ni ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun.

Akọroyin BBC Yoruba to ti balẹ silu Abẹokuta fi awọn aworan ransẹ nipa ibi ti igbaradi naa de duro.

Papa isere idaraya MKO Abiola ni Abẹokuta
Àkọlé àwòrán Gbogbo eto ti to saaju ibuwarawọle fun gomina nipinlẹ Ogun
Papa isere idaraya MKO Abiola ni Abẹokuta
Àkọlé àwòrán Dapo Abiodun ati Noimot Salaki Oyedele ni wọn yoo ma a bura fun gẹgẹ bi gomina ati igbakeji rẹ.
Papa isere idaraya MKO Abiola ni Abẹokuta
Àkọlé àwòrán Awọn ohun elo orin lọlọkan o jọkan ko gbẹyin nibi igbaradi naa.
Papa isere idaraya MKO Abiola ni Abẹokuta
Àkọlé àwòrán Awọn asofin ipinlẹ Ogun naa wa lara awọn ti wọn yoo ma burawọle fun ni Ọjọru

Ipinlẹ Kwara:

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ipinlẹ kan ko mu ayẹyẹ ibura awọn gomina tuntun ni kekere, ti wọn si fẹ ṣe ayẹyẹ ibura naa tilu-tifọn, amọ eyi ko ri bẹẹ rara ni ipinlẹ Kwara.

Idi ni pe wọọrọwọ ni wọn fẹ se ibura gomina ti ilu dibo yan, Abdulrahman Abdulrazak ti ipinlẹ Kwara, ti ayẹyẹ naa ko si ni kọja ile ijọba ipinlẹ naa.

Akọroyin BBC Yoruba to ti kalẹ silu Ilọrin fi ye wa pe, ko si pọpọsinsin kankan to n waye nipa ibura naa.

Ilorin
Àkọlé àwòrán Gbunkẹlẹ ni ayẹyẹ iburawọle ni ipinlẹ Kwara yoo jẹ lọla pẹlu bi ohun gbogbo se dakẹ rọrọ
Ilorin
Àkọlé àwòrán Awọn o sisẹ naa n gbaradi fun ọla

Akojọpọ aworan naa wa lati BBC