Fire: Táńkà epo méjì tó forí gbárí ló fa sábàbí iná ọ̀hún

Awọn ọkọ to jona ninu ijamba ina to waye ni marosẹ Ibadan si Eko Image copyright Trace

Nibi ti awọn alayọ ti n yọ fun ayẹyẹ ibura aarẹ Muhammadu Buhari ati tawọn gomina gbogbo lawọn ipinlẹ lọjọru, ijamba ati ofo nla lo n ba awọn eeyan kan to gba opopona marosẹ ibadan silu Eko kọja lọjọ naa.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajo-yajo lo fi ye ni pe, ijamba ọkọ kan to lagbara waye ni deede aago mẹwa ọjọru yii, ni abẹ afara Fidiwọ, lopopona marosẹ Ibadan silu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni, ọkọ tanka epo meji lo fi ori sọ ara wọn lojiji, ti ina si dahun lara wọn, eyi to mu ki eeyan marun fi ara pa yanna-yanna, ti ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ, ọkọ akẹru ati awọn ọkọ nla-nla si jona kọja ala.

Image copyright Trace

Amọ ko si ẹmi kankan to bọ ninu ijamba naa, ti awọn sisẹ alaabo atawọn araalu si ti pa ina ọhun.

Image copyright Trace

Sugbọn ijamba naa se okunfa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lopopona marosẹ Ibadan si ilu Eko ni ọjọru.

Image copyright Trace