Buhari, kò sí iṣẹ́. owó àti Oúnjẹ́ - Ọmọ Nàíjíríà figbe ta
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigeria Population: Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pọ̀ si jẹ́ ìpèníjà fún Buhari

Nibayii ti aarẹ Muhammadu Buhari ti sebura fun saa keji lori aleefa gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria, ọpọ awọn ọmọ orilẹede naa lo ti n fi igbe bọnu pe awọn ko ri isẹ se.

Lasiko ti wọ̀n n ba akọroyin BBC sọrọ, ọpọ eeyan lo tun ni awọn ni iwe ẹri to yẹ, amọ ti isẹ oojọ di isoro.

Fun apẹẹrẹ, ni ipinlẹ Rivers, ti epo rọbi sodo si julọ lorilẹede Naijiria, ọpọ olugbe ipinlẹ naa lo ni ko si owo lọwọ, ko si isẹ lati se, ti ebi si n pa awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, wọn ni awọn ni iya ati baba to yẹ ki awọn maa fun lowo, amọ ti ebi n pa wọn, nitori airi isẹ se awọn.

Amọ awọn miran tiẹ fikun pe, o lee jẹ iṣẹ kan pere ni awọn n ri se ni odidi ọṣẹ kan.

Ni bayii ti aarẹ Muhammadu Buhari si ti bẹrẹ saa keji rẹ lori aleefa