Nigeria Swearing in 2019: Makinde ní omi tuntun rú, ìgbà ọ̀tun dé sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Seyi Makinde

Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun nipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe alaye wi pe, asiko ti to fun imuṣẹ awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo idibo.

Makinde fidi ọrọ naa mulẹ ni Ọjọru, lẹhin to bura wọle gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, eyi to waye ni papa Iṣere Ọbafẹmi Awọlọwọ, tokalẹ si opopona Liberty niluu Ibadan.Ohun akọkọ ti gomina wọgile ni igbesẹ sisan ẹgbẹrun mẹta naira, ti awọn ọmọ ilẹ ẹkọ girama n san nipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣe alaye wi pe, ko bojumu ki awọn obi maa lakaka ki wọn to ri owo san fun awọn ọmọ wọn to n bẹ nile ẹkọ girama to jẹ ti ijọba.Ṣeyi Makinde tun mẹnuba pataki eto ẹkọ ati igbiyanju rẹ lati mu ko di irọrun f'awọn akẹkọọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

O fi kun ọrọ rẹ pe, bii ẹgbẹrun lọna irinwo akẹkọọ ni ko lanfani lati tẹsiwaju lẹnu ẹkọ wọn nipinlẹ Ọyọ, nitori ipenija owo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

O ni, "A ba obi awọn ọmọ to n lọ si ile ẹkọ girama to jẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ sọrọ, a si ṣe awari ẹ pe, gbogbo wọn n tiraka lati san ẹgbẹrun mẹta naira ti ijọba ana n gba lọwọ wọn. Lati asiko yii lọ, mo paṣẹ gẹgẹ bii gomina wipe ki wọn wọgile sisan iru owo bẹẹ."

O ni, "lasiko ipolongo idibo, bi a ti n lọ lati jọba ibilẹ kan si ikeji, a tẹti gbọ ẹdun ọkan ti awọn eeyan ni.

Mo mọ pe ohun ti awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ n beere fun ko pọ ju.

A ba awọn olokoowo sọrọ lori awọn ipenija to niṣẹ pẹluu owo ori sisan."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Population: Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pọ̀ si jẹ́ ìpèníjà fún Buhari

Awọn agbẹ naa sọrọ lori awọn ipenija ti wọn n dojuko nitori aisi awọn ohun elo amayedẹrun, paapa ọna to ja gara lasiko ti wọn ba fẹ ko ere oko.

Lasiko to n sọrọ lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju, Makinde ni lọwọlọwọ bayii, ipinlẹ Ọyọ ko lee san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fawọn osisẹ.

Image copyright Seyi Makinde

Sugbọn o salaye pe bi ohun gbogbo ba lọ botiyẹ, o ṣeeṣe ki owo osu oṣiṣẹ nipinlẹ Ọyọ jẹ eyi ti yoo pọ julọ loriẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Gomina tuntun naa wa dupẹ lọwọ awọn lẹgbẹlẹgbẹ, loyeloye to fimọ awọn adari ẹgbẹ oṣẹlu to ṣe atilẹhin fun un lasiko ipolongo idibo.

O ṣe ileri wipe, oun yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bii gomina to ni eero awọn ara ilu lọkan.

Image copyright Seyi Makinde

Lara awọn eeyan pataki to peju-pesẹ sibi ayẹyẹ iburawọle naa ni adajọ agba nipinlẹ Ọyọ, Muktar Abimbola ati aṣoju alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹkun guusu orilẹede yii.

Awọn yoku ni gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayoṣe, gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ Adebayọ Alao Akala, Olubadan ti ilẹ Ibadan Ọba Saliu Adetunji, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi ati bẹẹbẹẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka