Obasanjo: Ilé ni bàbá wà, kò wọkọ̀ òfurufu kankan

OlusegunObasanjo

Ko si ootọ kankan ninu iroyin kan to n ja rain-rain nilẹ pe, Aarẹ ana ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo, ni ori ko yọ ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu kan.

Iroyin naa, ti ko sọ ibi ti Obasanjọ n rinrin ajo lọ ṣalaye wipe, inu ọkọ ofurufu Ethiopian Airlines ni ori ti ko Obasanjọ yọ.

Ṣugbọn ni kete ti akọroyin BBC Yoruba kan si agbẹnusọ rẹ, Ọgbẹni Kehinde Akinyemi, lo ṣalaye wipe, aarẹ ana naa wa ni ẹgbẹ oun gan nilu Abẹokuta, ti ko si rin irinajo kankan kuro ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọna ati fi idi okodoro ọrọ yii mulẹ, Akinyẹmi tun yii ẹrọ ibaraẹnisọrọ naa soke, ki akọroyin BBC le gbọ ohun Obasanjọ, ti oun funra rẹ naa tun sọ pe, ko si oun to ṣe oun ati wipe oun ko lọ ibi kankan, tabi wọ ọkọ ofurufu kankan.

Akinyẹmi tun mu da BBC Yoruba loju pe, baba n gbalejo kan nile rẹ nilu Abẹokuta, lọwọlọwọ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Aarẹ ana naa ko lọ ibi iburawọle fun aarẹ Muhammadu Buhari to waye ni Ọjọru ni Abuja. Ọpọ eeyan lo ni o ṣeeṣe ki aarẹ ana naa rinrin ajo kuro ni Naijiria ṣugbọn, ọrọ agbẹnusọ rẹ fi han wipe, ile rẹ ni Abeokuta lo wa nigba ti iburawọle naa n lọ lọwọ ni Abuja.