Wo àwọn ìlérí tàwọn Gómìnà tuntun ṣe nínú ìbúra wọn

Image copyright NIG/PRESIDENCY
Àkọlé àwòrán Ọrọ mi koi tii ya - Buhari

Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni wọn ṣe ibura fun aarẹ Buhari lẹekeji pẹlu awọn gomina tuntun.

Ni Gbagede Eagle Square ni wọn ti bura fun aarẹ Buhari ati Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo to jẹ igbakeji rẹ nibi ti arẹ Buhari ko ti ka ọrọ akọsọ rẹ fun igba akọkọ ninu itan Naijiria.

Buhari búra láti bọwọ fún ofin Naijiria ni saa keji rẹ.

Awọn gomina ti wọn bura fun ni awọn ipinlẹ wọn naa ṣe awọn ileri kan fawọn ara ilu ni eyi to maa mu ki ọsan so didun ti wọn ba muu ṣẹ.

BBC Yoruba ṣagbeyẹwo diẹ lara awọn ileri ti wọn ti n fọn rere ẹ koda ṣaaju eto ibura wọn

Gomina Abdulrazaq Abdulrahman ti ẹgbẹ́ oṣelu APC ti wọn bura fun lati tukọ ipinlẹ Kwara titi di 2023 ṣeleri lati ṣatunṣe si eto ọgbin atawọn ohun amayedẹrun.

Àkọlé àwòrán Mo ṣetan lati mojuto ọrọ airiṣẹṣe awọn ọ̀dọ́ Kwara.

Oun lo le igba oṣelu PDP wọle ni Kwara pẹlu 'O tó gẹ'.

Bakan na lo tun ṣeleri lati tun awọn opopona ṣe ati mimojuto gbigbẹ odo Niger ki opin de ba omiyale ni Kwara paapaa lati ẹkun Patigi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Mo kéde ìlú-kò-fararọ lori eto ẹkọ ipinlẹ Yobe! - Mala

Gomina Mala Buni to maa tukọ ipinlẹ Yobe di 2023 ni oun ti ṣetan lati kọ opọlọpọ ile iwe alakọbẹrẹ ati ti girama pupọ sii.

O ni oun mọ ọṣẹ́ buruku tawọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti ṣe ni ẹkun yii to ti sọ eto ẹkọ wọn di nkan miran.

Image copyright @Bego
Àkọlé àwòrán Ijọba mi maa ṣeto ilana ti eto ẹkọ ipinlẹ Yobe a gunle lati isisinyi lọ

Maa tún àwọn Kọmiṣọnna tó ba ṣiṣẹ daadaa lò lẹẹkansii- Gomina Ebonyi

Gomina Dave Umahi ti ipinlẹ Ebonyi ṣeleri láti ṣe itọju awọn arugbo ni saa iṣejọba rẹ ikeji yii

Àkọlé àwòrán Maa gbiyanju lati san owo ọya oṣiṣẹ bi o ti yẹ

Gomina Dave lo gboriyin fawọn to baa ṣiṣẹ sẹyin pe wọn gbiyanju.

O ṣeleri lati ri si itọju awọn obinrin, ati lati mojuto eto ilera awọn ewe sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999

Ganduje: mo ṣetań lati pèsè ẹkọ ọ̀fẹ́ fawọn Akanda ẹ̀dá

Gomina ipinlẹ Kano to ṣe ibura lẹẹkeji, Abdullahi Umar Ganduje ni saa keji oun yii, awọn akanda ẹda a gbadun ẹkọ ọfe lati ile iwe alakọbẹrẹ titi de ti girama ni.

Image copyright @Yakasai
Àkọlé àwòrán Mo ṣetan lati tunra mu ninu iṣẹ ilu ti mo n ṣe ni Kano- Ganduje

Sanwo Olu- Ijọba mi ko ni yọ ẹnikẹni silẹ nipinlẹ Eko

Babajide Sanwo Olu to jawe olubori gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣe ọpọlọpọ ileri fawọn olugbe ipinlẹ Eko.

Àkọlé àwòrán Maa ṣiṣe pẹlu Hamzat igbakeji mi lati mu gbogbo ileri wa lasiko ipolongo ṣẹ fun ẹyin eeyan ipinlẹ Eko

Sanwo Olu ki àwọn eniyan ipinlẹ Eko fun ifarada si bi igba ti ri lasiko yii.

O ni ki wọn fọkan balẹ nitori didun ni ọsan ipinlẹ Eko yoo so nitori itẹsiwaju Eko lo jẹ oun logun.

Sanwo Olu ni ijọba oun yoo jẹ eyi to n gbọ ọrọ awọn ara ilu to dibo yan oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Mo wọgile gbogbo iṣẹ́ akanṣe tijọba to kọja lọ ti gbe sita tẹlẹ- Yahaya ipinlẹ Gombe

Gomina Inuwa Yahaya ti ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle bayii ni ipinlẹ Gombe.

Image copyright @yahaya
Àkọlé àwòrán A maa fiya to tọ jẹ àwọn ti wọn ko nkan ìní ijọba jẹ

Gomina tuntun fun ipinlẹ Gombe ni oun ko ni tẹlẹ awọn awuyewuye to ti n waye lati oṣu kẹta ni Gombe rara.

O ni ipade apero tẹẹkoto ti gomina PDP tẹlẹ n ṣe ni Gombe ti dopin bayii nitori pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ inu iṣejọba ipinlẹ Gombe bayii.

Ẹ darijin mi, Maa gbe igbesẹ to yẹ bayii- El Rufai

Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El Rufai to ṣe ibura lẹẹkeji lati tun tukọ ipinlẹ Kaduna ti tọrọ aforijin lọwọ awọn eniyan Kaduna.

Image copyright @Elrufai
Àkọlé àwòrán Ijọba mi ko ni gbe igbesẹ ipanilara ni saa keji yii

Nasir El Rufai ni oun n bẹbẹ silẹ nitori pe ijọba oun ti ṣetan lati gbe awọn igbesẹ akin to yẹ ni saa yii.

O ni oun n riran ọjọ iwaju rere to kun fun owó ati iṣẹ lọpọ yanturu fawọn eniyan ipinlẹ Kaduna ni saa iṣejọba keji oun yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Kaduna ni àjọ NYSC pín mi sí sùgbọ́n...'

Dapọ Abiọdun: Mo kọ̀ láti ko ẹ̀bi mi nikan si ijọba mi

Gomina tuntun ti wọn bura fun lati tukọ ipinlẹ Ogun di 2023 ni ko nii si adanikan jẹ ninu iṣejọba oun nipinlẹ Ogun rara.

Àkọlé àwòrán Maa nu gbogbo omije atẹyinwa nù loju àwọn eniyan ipinlẹ Ogun ni -Dapo

Dapo Abiọdun ni oun bura lati fi ootọ inu ṣiṣẹ si alaafia ati idagbasoke awọn eniyan ipinlẹ Ogun lapapọ ni.

O ni oun ko ni da ẹnikẹni ninu adehun ati awọn ileri ti oun ti ṣe ṣaaju idibo.

Ni papa iṣere MKO Abiola to wa ni Kutọ, nilu Abẹokuta ni Dapo ti ṣeleri lati ṣe atunṣe si igbe aye awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Gbogbo olùdíje Ogun fi dá àwọn ènìyàn lójú pé...'

Alaafia eniyan Enugu lo jẹ mi logun -Ugwuanyi

Image copyright @ugwuanyi
Àkọlé àwòrán Mo kọ láti gba ẹmi imọ-tara-ẹni-nikan-laaye ni Enugu

Gomina Ifeanyi Ugwuanyi lo jawe olubori labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Enugu ninu idibo ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta, ọdun yii.

O ni oun yoo gbajumọ eto aabo awọn eniyan oun ni saa keji ti o ṣẹṣẹ ṣe ibura rẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Mo wọgile #3,000 tawọn akẹkọọ ipinlẹ Oyo n san - Makinde

Seyi Makinde to jawe olubori labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo tukọ ipinlẹ Oyo titi di ọdun 2023.

Àkọlé àwòrán Eto ẹkọ ọfẹ ti bẹre nipinlẹ Oyo bayii

Ìjọba Naijiria ti ṣe ìlérí lóríṣíiríṣi látẹnu àwọn Gomina tuntun ti wọ́n ṣe ìbúra ni àná ni èyí tó lè mú ọsàn so dídùn fáwọn ara ilu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde