Africa Free Trade Zone: Kò sí ìdènà láti kó ọjà láti orílẹ̀èdè kan sí òmíràn

Àkọlé àwòrán Agbekalẹ adehun yii ni wọn gba pé o maa jẹ ki ọja tita tubọ rọrun fawọn olokowo keekeeke

Naijiria jẹ orilẹ-ede ti eto ọrọ aje ẹ tobi julọ nilẹ Adulawọ.

Adehun yii laarin awọn olori ilẹ Afrika ni wọn gba pé yoo mu ọja tita rọrun sii fawọn olokowo keekeeke nigba ti wọn ko ba san owo ori ọja ni awọn ẹkun ti ọrọ kan.

Wọn tun gba pe adehun yii yoo jẹ ki ibaṣepọ awọn olokowo lati orilẹ-ede ilẹ̀ Adulawọ dan mọran sii.

Ni oru Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn, osu Karun un, ọdun 2019 mọjumọ ọjọ keji rẹ, tii se Ọjọbọ, ni agbekalẹ ibudo okoowo ọfẹ fun ilẹ Afirika, ti ko ni owo ori ninu gberasọ, eyi to jẹ eto okoowo to tii tobi julọ lati igba ti wọn ti bẹrẹ ajọ eleto okoowo lagbaye (World Trade Organisation).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀdéhùn ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Afirika le lẹ́yìn

Sugbọn bi ọpọ anfaani se sodo sinu eto okoowo ọfẹ laarin awọn orilẹ-ede nilẹ Afirika yii, orilẹ-ede Naijiria ati Cameroon ko si lara awọn orilẹ-ede mẹtalelogun ti wọn ti buwọ luu.

Aarẹ Buhari ṣalaye fun Cyril Ramaphosa ti ilẹ South Africa pé oun ko ni pé tọwọbọ iwe adehun naa.

O ni oun kan fẹ ṣe iwadii sii lori abajade iru igbesẹ bẹẹ ni.

Òru òní, ọjọ́rú ni àdéhùn níní ibùdó olókoòwò ọ̀fẹ́ nílẹ̀ Adúláwọ̀ bẹ̀rẹ̀ ni èyí tí Aarẹ Buhari ti Naijiria kòì tíì fọwọ́síi.

Image copyright @vera
Àkọlé àwòrán Àwọn obinrin yoo ri anfaani to pọ jẹ - Vera Songwe

Akọṣẹmọṣẹ Vera Songwe to jẹ akọwe ajọ iṣokan agbaye UN lori eto ọrọ aje nilẹ Afrika sọrọ kikun lori anfaani fawọn oloko owo obinrin.

O ni ti awọn orilẹ-ede mẹrinlelaadọta ilẹ Adulawọ ba fọwọ si adehun yii, yoo rọrun fawọn olokowo paapaa obinrin lati rin laifoya lati orilẹ-ede kan si ikeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBarister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa

Vera Songwe gba pé olori isọro okowo nilẹ Adulawọ ni eto irinna.

O ni ọkan awọn obinrin yoo balẹ sii nidi okowo wọn lati ẹkun kan si ikeji ni eyi ti yoo mu ibugbooro ba okowo wọn sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Vera ni eto aabo ati igbọraẹni ye yoo wa laarin wọn sii nidii ọja wọn nigba ti owo ibode, owo ori ọja ati owo ori ọlọja ba ti kuro nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?