Organisation of Islamic Cooperation: Àǹfààní wo ló wà nínú ẹgbẹ́ OIC?

Awọn ẹgbẹ OIC Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán OIC n ṣepade

Wọn da ẹgbẹ Organisation of Islamic Cooperation ti ọpọ mọ si OIC silẹ lọdun 1969 pẹlu orilẹede mẹtadinlọgọta.

Ọrilẹede mẹtalelaadọta ninu awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ OIC lo jẹ awọn orilẹede ti awọn ẹlẹsin musulumi ti pọ ju.

Ẹgbẹ OIC ni aṣoju ni ajọ iṣọkan agbaye ati ajọ ilẹ alawọfunfun ti wọn n pe ni European Union.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Population: Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pọ̀ si jẹ́ ìpèníjà fún Buhari

Kinni erongba OIC?

Gẹgẹ bi adehun ti wọn ṣe, ẹgbẹ OIC pinnu lati maa gbe ohun to jẹ mọ ẹsin musulumi larugẹ lawọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ OIC tun pinnu pe awọn yoo ṣe imugbooro aṣa ati imọ sayẹnsi lawọn orilẹede to jẹ ọmọ ọhun.

OIC tun pinnu lati mu eto aabo lọkun-kundun ati lati lepa alaafia kaakiri gbogbo orilẹede ti ẹgbẹ naa wa.

OIC tun pinnu lati maa ṣe igbelarugẹ eto ẹkọ imọ-ijinlẹ ni gbogbo orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

Akitiyan OIC lori awọn to ṣatipo

Ẹgbẹ OIC ti gbalejo awọn atipo bi miliọnu mejidinlogun lati igba ti ẹgbẹ ọhun ti wa titi di ọdun 2010

Awọn orilẹede to jọ ọmọ ẹgbẹ OIC ti n gbalejo awọn atipo lati awọn orilẹede ti rukerudo ti n ṣẹlẹ lati ọdun 2010

Image copyright Wilkipedia
Àkọlé àwòrán Kinni o mọ nipa OIC?

Lọdun 2011 ni ẹgbẹ OIC yi orukọ rẹ pada Organisation of Islamic Conferencde ssi Organisation of Islamic Cooperation.

Buhari mórí lé Saudi lẹ́yìn ìbúrawọlé fún sáà kejì

Lẹyin iburawọle fun saa keji l'Ọjọru, Aarẹ Muhammadu Buhari mo ri le orilẹ-ede Saudi Arabia lonii Ọjọbọ.

Image copyright Facebook/Femi Adesina
Àkọlé àwòrán Aarẹ Muhammadu Buhari n lọ fun ipade OIC

Aarẹ n lọ fun apero ẹgbẹ Organisation of Islamic Cooperation ti ọpọ mọ si OIC ti yoo waye lọjọ Ẹti niluu Makkah.

Ọjọ keji, oṣu kẹfa ni Aarẹ Buhari yoo pada si orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Population: Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pọ̀ si jẹ́ ìpèníjà fún Buhari

Ninu atẹjade ti oludamọran agba fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu sita, Aarẹ Buhari yoo sọrọ nibi apero ọhun.

Atẹjade naa sọ pe aarẹ yoo sọrọ lori iṣepataki ki awọn orilẹ-ede to jẹ ọmọ ẹgbẹ OIC wa ni iṣọkan lati le jọ koju ipenija bi awọn agbesumọmi ti wọn n da rogbodiyan kalẹ kaakiri.

Aarẹ Buhari yoo tun sọrọ lori anfaani to wa nibi idokowo awọn orilẹ-ede ilẹ okere ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Buhari ni aarẹ orilẹ-ede Naijiria kẹta ti yoo lọ fun apero ẹgbẹ OIC lẹyin oloogbe aarẹ tẹlẹ ri, Umaru Yar'Adua ati aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti kọkọ lọ fun irun apero bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Jigawa, Mohammed Badaru Abubakar, Gomina Oṣun, Gboyega Oyetola ati Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello wa lara awọn ti yoo kọwọ rin pẹlu aarẹ lọ ilẹ Saudi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?