Nigeria Swearing in 2019:Olókoòwò tó dáńtọ́ ni gómìnà Ogun tuntun

Ọmọọba Dapọ Abiọdun
Àkọlé àwòrán Ori lo mọ ọlọrọ, ori lo mọ ọba.

Ori lo mọ ọlọrọ, ori lo mọ ọba.

Ori ẹni si lo n gbe ni, ti a fi de ade owo, ori ẹni naa lo n gbe ni, ti a fi tẹ ọpa ilẹkẹ, ori yii naa si lo gb'Ọmọọba Dapọ Abiọdun, to fi di gomina tuntun ni ipinlẹ Ogun.

Ọjọ Kọkandinlọgbọn, osu Karun un, ọdun 1960, ni idile Ọba kan nilu Ipẹru Rẹmọ gba alejo ọmọ tuntun jojolo, eyi to tọ Dokita Emmanuel Abiodun ati aya rẹ, Victoria wa, eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni Adedapọ Abiọdun.

Ohun to si tun yani lẹnu julọ ni pe, nigba to ku ọdun kan pere ki Dapọ yii pe ẹni ọgọta ọdun, ni ori gbe e de ipo gomina, to si bura wọle ni ọjọ yii kan naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn niwọn igba to jẹ pe ọjọ ti eeyan ba gun kọ lo n kan ọrun, ojo ti n pa igun Dapọ bọ nidi ko lee jẹ eeyan laye, ọjọ ti pẹ.

O ti ko ipa ribiribi ni agbọn kan abi omiran, ko to de ipo gomina.

Àkọlé àwòrán Ori lo mọ ọlọrọ, ori lo mọ ọba.

IMỌ ẸKỌ ATI ILEẸKỌ TI DAPỌ ABIỌDUN LỌ:

Dapọ Abiọdun lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, ko to morile ileẹkọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile Ifẹ, nibi to ti kẹkọ gboye imọ nipa iṣẹ ẹrọ.

Lẹyin eyi lo tẹkọ ofurufu leti lọ sile ẹkọ fasiti Kennsaw ni Atlanta Georgia, lorilẹ-ede Amẹrika.

Nibẹ lo tun ti gba imọ kun imọ nipa iṣiro owo, to si ni iwe ẹri imọ ijinlẹ keji, taa mọ si Masters.

Ni kete ti Dapọ pada sile lati oke okun, lo tun morile ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Ekiti lati gba oye ọmọwe, ti a mọ si PhD ninu imọ nipa ìnáwò, to si tun gba oye ọmọwe keji lẹka imọ nipa akoso okoowo nile ẹkọ fasiti Adeleke to wa nilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun.

IRIRI DAPỌ LẸNU IṢẸ:

Lẹyin ti Dapọ pari iwe lo di gbajugbajaolokoowo ati oloselu. Oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ kan to wa fun ipese ohun amuṣagbara.

Bakan naa ni Dapọ jẹ odu, ti kii ṣe aimọ fun oloko ni ẹka katakara awọn eroja epo rọbi ati afẹfẹ idana gaasi, to si ni ileeṣẹ aladani tiẹ fun eroja epo rọbi.

Àkọlé àwòrán Ori lo mọ ọlọrọ, ori lo mọ ọba.

IRINAJO RẸ NINU ETO IṢELU:

Lọdun 1998, ẹrin pa ẹẹkẹ Dapọ, ti wọn si dibo yan-an gẹgẹ bii aṣofin agba sile aṣofin ni Abuja, lati lọ ṣoju ẹkun idibo rẹ, labẹ ẹgbẹ oṣelu UNCP.

Oniruuru igbimọ si ni Dapọ ti ṣiṣẹ lasiko to wa ni aṣofin agba naa.

Dapọ Abiọdun tun tirakalọdun 2015, to si tun pada dije sile aṣofin agba fun saa keji ni ẹkun ila oorun Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, amọ to fidi rẹmi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Ṣugbọn ori gbe Dapọ de ibi giga, eyi to ju ipo kọja ero rẹ, nigba to dije wọle bii gomina lọdun 2019, to si jawe olubori gẹgẹ bii gomina tuntun fun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

Ọmọlẹyin Kristi to dantọ ni Dapọ Abiọdun n ṣe, to si gbagbọ pe Ọlọrun lo gbe oun de ipo gomina, laifi ti ọpọ atako to dide si oun ṣe.