Adeleke: APC ní ìdájọ́ ileẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kò fún Adeleke ní ìrètí kankan

Ademola Adeleke Image copyright Ademola Adeleke

Lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun wọgile idajọ to ni Adeleke ko yẹ lati du ipo gomina, eyi tí Wahab Raheem and Adam Habeeb gbe wa siwaju rẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ti fesi wipe, idajọ naa ko tumọ si wipe, Adeleke yoo di gomina.

Akọwe ẹgbẹ naa ni Ipinlẹ Osun, Kunle Oyatomi sọ fun BBC Yoruba wipe, igbẹjọ naa ko yẹ ireti ẹgbẹ APC wipe, Adeleke ko le de ipo gomina ipinlẹ naa lailai.

Oyatomi ni, "Ṣebi ki i kuku ṣe ẹgbẹ wa APC lo gbe ẹjọ yii lọ iwaju ile ẹjọ giga Abuja, eyi to ni Adeleke ko ni ẹtọ lati dije fun ipo gomina ni ibẹrẹ pẹpẹ. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn olupẹjọ mejeeji naa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti ẹ ba ranti, ile ẹjọ giga ilu Abuja da ẹjọ lọjọ keji osu kẹrin ọdun 2019 pe, oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ọsun fun ẹgbẹ oselu PODP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ko lẹtọ lati du ipo gomina nitori ko ni iwe ẹri iwe mẹwa.

Ṣugbọn nigba ti ile ẹjọ kotẹmilọrun do doju ẹjọ naa bolẹ gbe idajọ rẹ kalẹ, igbimọ ẹlẹni mẹta naa lo panupọ kede pe ile ẹjọ giga naa ko yẹ lati dajọ pe Adeleke ko pari ile ẹkọ girama, ati pe, irọ lo pa lori iwe ẹri to ni oun ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Adajọ to lewaju igbimọ ẹlẹnu mẹta naa, Emmanuel Agim, tọkasi kudiẹ-kudiẹ to wa ninu idajọ akọkọ naa, paapa lori bi ileẹjọ giga ọhun se gba pe oun ni aṣẹ lati gbọ ẹjọ naa, lẹyin ọjọ mẹrinla ti ofin la kalẹ lati pe ẹjọ saaju idibo.

Adajọ Agim ni awọn olupẹjọ ko tẹle ohun ti ofin ilẹ wa naa la kalẹ nidi pipe ẹjọ, ti adajọ to gbọ ẹjọ naa nile ẹjọ giga pẹlu tun kuna lati gbe idajọ rẹ kalẹ laarin ọgọrin ọjọ

Adajọ naa wa kede pe kawọn olupẹjọ lọ san milliọnu mẹta naira fun Adeleke fun bi wọn ṣe da a laamu.