Makinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san
Tilu tifọn ni awọn osisẹ nipinlẹ Ọyọ fi n ki gomina tuntun, Onimọ-ẹrọ Seyi Makinde kaabọ si ọọfisi ni aarọ Ọjọbọ.
Bakan naa ni eto orin iyin ati adura waye lati mu ki ijọ̀ba gomina Seyi Makinde se aseye ti alakan n sepo.
Nigba to n sọrọ lori bi gomina tuntun naa se wọgile ẹgbẹrun mẹta naira owo iranwọ eto ẹkọ tawọn akẹkọ ileẹkọ girama n san, Alaga ẹgb osisẹ nipinlẹ Ọyọ, Bayọ Titilọla Sodo kan saara si Makinde pe o mu ileri to se, lati wọgile owo naa sẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa ni Sodo tun se sadankata si Makinde pe, o fọwọ gbaya pe awọn osisẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ seese ki wọn gba owo osu to ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lọ.
Sugbọn nigba to n fesi lori asẹ ti Makinde pa pe, kawọn alaga ijọba ibilẹ gbogbo to wa nipinlẹ Ọyọ ko aasa wọn kuro ni ọọfisi, agbẹnusọ fawọn alaga ijọba ibilẹ naa, Ọmọọba Ayọdeji Abass Alẹsinlọyẹ fajuro lori ipinnu Makinde naa, to si ni gomina tuntun ọhun tẹ ofin loju laarin wakati meji pere to seleri lati gbe ofin Naijiria ro.