Rochas Okorocha: Fayose rọ Rochas Okorocha, Ibikunle Amosun láti jọ̀wọ́ ara wọn fún EFCC

Rochas Okorocha and Ayo Fayose Image copyright Twitter/Rochas Okorocha/Ayo Fayose
Àkọlé àwòrán Fáyòṣe ní kò yẹ kí ọ̀rọ̀ EFCC ó ya Rochas Okorocha lẹ́nu

Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayọdele Fayoṣe ti ke si gomina to ṣẹṣẹ fi ipo silẹ ni ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha pe, ko tete jọwọ ara rẹ silẹ fawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC, to ba jẹ pe lootọ ni wọn wa lati muu.

Fayoṣe sọrọ yii ni Ọjọbọ lẹyin ti iroyin bọ sita pe Rochas Okorocha pẹlu iyawo rẹ ti wọ gbaga ajọ EFCC, bi o tilẹ jẹ pe, ajọ naa ti kede sita pe ko si ohun to jọọ, oun ko mu Okorocha.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fayose fi sita loju opo twitter rẹ pe, oun ki Rochas Okorocha kaabọ si ẹgbẹ awọn gomina ti EFCC n wa kiri. O ni o yẹ ki Rochas o mọ pe irufẹ ọjọ bayii yoo waye lai jẹ pe ẹnikẹni wi fun un.

"Amọṣa, mo ki i kaabọ si ẹgbẹ awọn ti EFCC n wa, mo si tun rọ ajọ naa lati maṣe gbagbe Amosun naa."

Bi ẹ ko ba gbagbe, gomina Ayọ Fayoṣe naa n jẹjọ niwaju ile ẹjọ lori awọn ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an.

Ni kete to pari saa iṣejọba rẹ lo ti lọ jọwọ ara rẹ fun ajọ naa ni ọdun 2018.