Ọkùnrin kan bẹ́ orí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Cross River, ni ará ìlú bá sin ín láàyè

Awọn ọlọpaa Naijiria Image copyright Saharareporters
Àkọlé àwòrán Arákunrin náà ti ara rẹ̀ mọ inu ilé, ó sì ń kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ òun, yóò fara gbọgbẹ́ bí i ti ẹ̀gbọ́n òun.

Arákunrin náà ti ara rẹ̀ mọ inu ilé, ó sì ń kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ òun, yóò fara gbọgbẹ́ bí i ti ẹ̀gbọ́n òun.

Iroyin ni arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ojemba fi ibinnu bẹ ori ẹgbọn rẹ ni abule Liokom to wa Ijọba Ibilẹ Yala ni Ipinlẹ Cross River.

Awọn ara abule naa ti da a lẹjọ oro, wọn si sin in láàyè pẹlu oku ẹgbọn rẹ naa.

Awọn ara abule naa ni awọn gbe igbesẹ naa nitori pe eewọ ni iku ti Ojemba fi pa ẹgbọn rẹ, Obok.

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Austine Agbonlahor ni oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san

Ṣugbọn ki lo faa ti Ojemba fi bẹ ori ẹgbọn rẹ?

Iroyin ọsẹ diẹ ṣẹyin ni iya awọn ọkunrin mejeeji ku. Iroyin ni awọn mejeeji ko ja rara ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Ara adugbo ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni ṣe ni Obok pada de lati ode ti iyawo rẹ si gbe ounjẹ siwaju rẹ.

Obok n jẹun lọwọ ni a gbọ pe Ọjemba ba fi ada ge ori ẹgbọn rẹ bọ silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOkùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

Awọn ara adugbo ni ariwo iyawo oloogbe naa ni awọn gbọ ti wọn si sa lọ ibi iṣẹlẹ naa nibi ti wọn ti ba Obok ninu agbara ẹjẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBarister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa

Igba ti wọn gbiyanju lati mu Ojemba, ṣe ni arakunrin naa ti ara rẹ mọ inu ile ti o si n kilọ pe ẹnikẹni to ba sun mọ oun, yoo fara gbọgbẹ́ bí i ti ẹgbọn oun.

Ṣugbọn awọn ọdọ mẹta ni abule naa ja lẹkun wọle, wọn si ra afẹsunkan naa mu, ki wọn to de e lọwọ ati ẹsẹ.

Ṣe ni wọn gbe e sinu iho ti wọn ti gbẹ́ fun oku ẹgbọn rẹ. Wọn sọ ọ sinu iho naa, ki wọn to gbe oku ẹgbọn rẹ lu u laya, ti wọn si fi yẹpẹ bo o mọlẹ laaye.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: