N11trn subsidy: Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé owó ìrànwọ́ epo lè kọ Second Niger Bridge méjìléláàdọ́ta?

Image copyright Pulse
Àkọlé àwòrán Kíni N11trn owó ìrànwọ́ epo tí ìjọba àpapọ̀ san fún àwọn agbépo lè rà?

Lọdun 2012, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria jade lati fi ẹhonu han lori ipinnu ijọba aarẹ Goodluck Jonathan nigba naa lati yọ owo iranwọ epo (subsidy).

Ṣugbọn ni Ọjọbọ, Ile Igbimọ Aṣofin Agba Naijiria fi to ọmọ Naijiria lẹti pe ijọba apapọ na triliọnu mọkanla naira gẹgẹ bii owo iranwọ epo rọbi (subsidy) ni ọdun mẹfa.

Ṣugbọn ki ti ẹ ni iye owo yii tumọ si? Ki ni owo yi le da ṣe ni orilẹ-ede Naijiria?

Àwọn aworan yii ṣe alaye bi owo yii ṣe to:

1. Triliọnu mọkanla yoo kọ aadọta afara keji Niger (Second Niger Bridge).

Nigba ti ijọba apapọ bẹrẹ iṣe lori afara Niger keji (Second Niger Bridge) wọn sọ pe iṣẹ akanṣe naa yoo gba igba ati ogun biliọnu.

Image copyright Ministry of Works

Ta a ba pin triliọnu lọna mọkanla owo iranwọ epo yii si iye owo ti wọn fẹ fi kọ afara yii, yoo kọ to aadọta iru afara naa.

Ki i tun ṣe eyi nikan, àwọn ijọba China ni afara ori omi to gun ju ni agbaye to wa ni orilẹ-ede China kò ná wọn ju triliọnu meje o le diẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Population: Báwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe ń pọ̀ si jẹ́ ìpèníjà fún Buhari

Odun 2018 ni wọn pari afara naa ti yoo maa gbe awọn arinrinajo lati Hong Kong lọ Zhuhai. Kilomita marunlelaadọta ni afara naa.

Àkọlé àwòrán Kilomita marunlelaadọta ni afara naa

2. Owo iranwọ epo naa le kọ ibudo papakọ ofurufu to din diẹ niẹgbẹrin

Ijọba apapọ fi to awọn oniroyin leti laipẹ yii pe wọn ti pinnu lati wo ibudo (terminal) papakọ ofurufu Murtala Muhammad to wa ni Ipinlẹ Eko.

Ijọba ni biliọnu mẹrinla ni iṣẹ naa yoo gba.

Ti ijọba ba ni ki wọn fi owo iranwọ epo rọbi kọ iru ibudo papakọ ofurufu yii, yoo fẹ kọ to ẹgbẹrin iru rẹ.

3. Yoo kọ mejidinlogoji ile iwosan igbalode iru eyi to wà ni Texas yii

Ile iwosan yii ni Ile Iwosan Southwestern to wa ni fasiti Texas ni orilẹ-ede Amerika.

Ile iwosan naa wa lara eyi to dara ju ni agbaye nitori awọn irinṣẹ igbalode to wa nibẹ.

Image copyright University of Texas Southwestern hospital

O din diẹ ni ọọdurun biliọnu naira ti wọn fi pari ile iwosan naa.

Iye owo iranwọ epo yii yoo kọ iru ile iwosan yii mejidinlogoji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Iye ile iwe meloo ni ẹ ro pe triliọnu mọkanla yii le kọ lagbegbe ti yin?

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n kọminu lori bi ijọba ṣe n san iru owo bayii lai nii fi ṣe awọn ibo miran ti wọn gab pe o le ṣe anfaani ti wọn ba naa sibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde