JAMB: Ẹ̀ṣùn oníkókó mẹ́jọ ni EFCC fi kan Philomina àtàwọn 5 míràn

Philomina

Ajọ EFCC lo gbe arabinrin Philomina atawọn to ku lọ sile ẹjọ lori sise owo ajọ to n sedanwo JAMB kumọ-kumọ.

Arabinrin Philomina Chieshe ni wọn fẹsun kan pe, o na owo ajọ to n mojuto ṣiṣe idanwo igbaniwọle sile iwe giga ni Naijiria, JAMB.

Miliọnu lọna mẹrindinlogoji ni wọn ni pé o gbe nigba naa ti wọn si ni o sọ pé ejo lo gbe owo naa mi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyalẹnu lo jẹ fawọn eeyan nigba ti obinrin yii gbọrọ naa kalẹ niluu Makurdi, nipinlẹ Benue lọdun 2018.

Ile ẹjọ giga l'Abuja ni wọn gbe obinrin naa lọ pẹlu awọn meji miiran, ti wọn si fi ẹsun onikoko mẹjọ kan wọn.

Ṣugbọn Philomina atawọn meji yoku lawọn o jẹbi ẹsun ti kan wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Agbẹjọro wọn rọ ileẹjọ lati pe ki adajọ fun wọn ni beeli nibi igbẹjọ ọhun.

Ṣugbọn adajọ Peter Afen sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹta, oṣu kẹfa, bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn si wa ni kolo ajọ EFCC titi di ọjọ naa.