NURTW Oyo: Ìwà ìdàlùrù ní Ibadan ló mú kí Makinde gbẹ́sẹ̀ lé NURTW

Alaga ẹgbẹ awakọero nipinlẹ Ọyọ Image copyright @Oyoaffairs

Ẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ Ọyọ tijọba fofin de, ti fesi lori bi ijọba ipinlẹ Ọyọ se fi ofin de ẹgbẹ naa lọjọ keji ti gomina Seyi makinde gba ọpa asẹ, to si ni pe eegun rẹ ko gbọdọ sẹ mọ jakejado ipinlẹ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Ọyọ, Waheed Adeọyọ, ti gbogbo eeyan mọ si Ejiogbe, ẹni ti akọwe ẹgbẹ, Sunday Yeye gbẹnu rẹ sọrọ, salaye pe laipẹ ni awọn yoo pe ipade gbogbo ọmọ ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, lati fi asẹ ijọba naa to wọn leti

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ejiogbe wa rọ awọn awakọ ero nipinlẹ Ọyọ lati mase fa wahala kankan nitori asẹ ijọba yii, amọ ki wọn maa ba isẹ oojọ wọn lọ nitori asẹ ijọba naa ko di awọn lọwọ lati sisẹ oojọ awọn, sugbọn awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ ni asẹ yii ba wi.

Image copyright Adedayo Owolabi

Bakan naa lo fikun pe, "igbimọ̀ alasẹ́ ẹ́gbẹawakọ ero nipinlẹ Ọyọ ti fi isẹlẹ yii to olu ile ẹgbẹ NURTW ni Abuja leti, bi o tilẹ jẹ pe wọn wa nilu Mecca lọwọ-lọwọ fun eto Umura."

"Ni kete ti awọn alasẹ ẹgbẹ ni Abuja ba si ti de si orilẹede yii ni wọn yoo wa kan si gomina Makinde lati yanju ọrọ yii ni itubi n nubi.

Image copyright @Oyoaffairs

Seyi Makinde fofin de ẹgbẹ NURTW Ọyọ, o gbakoso gareji ọkọ

Bẹẹ ba gbagbe, owurọ ọjọ Ẹti ni ijọba ipinlẹ Ọyọ kede pe oun ti fofin de ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ, NURTW, to si pasẹ pe eegun wọn ko tun gbọdọ sẹ mọ.

Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, olori osisẹ lọọfisi gomina, oloye Bisi Ilaka salaye pe iwa idaluru ti awọn ẹgbẹ ọlọkọ ero yii n hu lawọn agbegbe kan nilu Ibadan lo fa sababi igbesẹ ijọba naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo fikun un pe, ikankan ninu awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ ọlọkọ ero naa ko gbọdọ safihan ara wọn mọ laarin igboro jakejado ipinlẹ Ọyọ.

Ilaka wa rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ pẹlu alaafia laisi ifoya kankan, pẹlu afikun pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gba akoso awọn ibudokọ gbogbo yika ipinlẹ Ọyọ, ti eegun awọn asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero ko si gbọdọ sẹ mọ nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si olori eto iroyin fun ipolongo ibo gomina Seyi Makinde, Ọmọọba Dọtun Oyelade, o sọ fun wa pe ijọba yoo fi akọsilẹ iroyin nipa igbesẹ rẹ ọhun sita laipẹ.

Bo ba si se n jade, ni a maa mu iroyin rẹ wa fun un yin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san