Oyo: Bisi Ilaka ní ìdìbò àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ lòdì sófin

Awọn alaga ijọba ibilẹ ni Ọyọ pẹlu Abiọla Ajimọbi Image copyright Oyo State Government

Ijọba Ipinlẹ Oyo ti salaye idi abajọ ti Gomina Ṣeyi Makinde fi paṣe wi pe, ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ naa fi ipo wọn silẹ ni kiakia.

Olori oṣiṣẹ ọba lọfiisi gomina, Oloye Oyebisi Ilaka sọ fawọn akọroyin lọjọ Ẹti pe, idibo ijọba ibilẹ to waye lasiko ijọba Gomina ana, Abiola Ajimọbi ko wa ni ibanu pẹlu ofin, ati pe eto idibo to gbe awọn alaga ibilẹ naa wọle lodi si aṣẹ ileẹjọ.

Oloye Ilaka ṣalaye pe, ijọba to ṣẹṣẹ gori aleefa ṣetan lati tele ofin ninu iṣejọba ipinlẹ Oyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori oṣiṣẹ ọba lọfiisi gomina sọ pe, ijọba n reti ki awọn alaga naa lọ si ileẹjọ, ti igbesẹ yii ko ba tẹ wọn lọrun.

O fikun ọrọ rẹ pe, ijọba ti yan awọn amofin to dantọ lati ṣoju rẹ, ti ọrọ naa ba dọrọ ileẹjọ.

Image copyright Seyi Makinde

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un ọdun 2019, to jẹ ọjọ ti wọn bura fun un gẹgẹ bi gomina tuntun ni ipinlẹ Ọyọ, ni Gomina Seyi Makinde paṣẹ pe ki gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ naa fi ipo wọn silẹ ni kiakia.

Gomina Makinde kede ọrọ naa latẹnu olori oṣiṣẹ rẹ, Bisi Ilaka, pẹlu afikun pe ki awọn alaga naa gbe iṣakoso silẹ fun awọn olori awọn oṣiṣẹ tabi oludari agba lawọn ijọba ibilẹ wọn.

Gomina Seyi Makinde tun paṣẹ pe ki gbogbo igbimọ oluṣakoso ni awọn ileeṣẹ ati lajọ-lajọ to jẹ tijọba Ọyọ di tituka.

Seyi Makinde kò ní ẹ̀tọ́ láti yọ alága ìjọba ìbílẹ̀ tì kò yàn sípò - Amòfin

Sugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ gomina tuntun naa,, Amofin Oludare Falana sọ pe, Gomina Makinde ko ni ẹtọ kankan labẹ ofin orilẹede Naijiria lati yọ alaga ijọba ibilẹ ti kii ṣe oun lo yan-an sipo.

O ṣalaye pe abala keje ofin orilẹede Naijiria to sọrọ nipa awọn ijọba ibilẹ pe, bi a ṣe n dibo yan awọn aṣofin tabi gomina naa ni awọn alaga ijọba ibilẹ ni ẹtọ lati jẹ yiyan si ipo.

Image copyright Oyo State Government

"Eyi naa ni ofin eto idibo faramọ. Ti mejeeji si sọ pe awọn alaga ijọba ibilẹ ti awọn ara ilu dibo yan ni ẹtọ lati pari saa iṣakoso wọn."

O ni "nibi ti ọrọ de bayii, awọn alaga ti Makinde sọ pe ko fi ipo silẹ ni ẹtọ lati lọ sile ẹjọ."

O ni "o jẹ ohun to ku diẹ kaato pe, Seyi Makinde gẹgẹ bi gomina tuntun ti ko ti i yan agbẹjọro ijọba nipinlẹ naa, n yọ alaga nipo. Nitori pe agbẹjọro agba naa lo yẹ ko tọ ọ sọna lori ọrọ naa. "

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Oṣu Karun un, ọdun 2018 ni gomina to ṣẹṣẹ fi ipo silẹ nipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi, ṣeto idibo ijọba ibilẹ.

Idibo naa waye lẹyin ọdun bi i mẹwa ti iru rẹ ti waye kẹhin nipinlẹ naa. Ọdun 2007 ni idibo ijọba ibilẹ waye kẹhin lasiko ti Adebayọ Alao Akala fi wa ni ipi gomina.

Lọgan to kede aṣẹ yii naa ni awọn alaga ijọba ibilẹ ti ọrọ kan ti ṣepade, ti awọn naa si n leri peko si ẹnikẹni to le ṣi awọn nidi kuro ni ipo alaga.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san

Awọn alaga naa ṣapejuwe igbesẹ Makinde gẹgẹ bi aṣẹ onikumọ.

Ọkan lara awọn alaga naa, Abass Alẹṣinlọyẹ sọ pe awọn alaga naa ti kọwe si gbogbo awọn to le ranwọn lọwọ lori ọrọ naa.