UEFA Champions League 2019: ilé ló máa bọ́sí fàwọn ọmọ Afrika loni

Aworan awọn agbabọọlu Afirika to wa ni ikọ Liverpool ati Tottenham hotspur Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ Afirika mẹfa lo wa ninu ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii

Agbábọ́ọ̀lù ọmọ Áfíríkà mẹ́fà tó ṣeéṣe kó gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions league lónìí.

Loni ni ko ni dọla ti agbaye yoo mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo pegede, fi gbọọrọ jẹ ka ninu idije UEFA champions league ti ọdun 2019.

Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ati Tottenham ni yoo maa figagbaga ni ipele aṣekagba idije naa lalẹ ọjọ Satide.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa, eyi o wu ko gbe'gba oroke laarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii, o daju ṣaka pe ọwọ ilẹ Afirika ko ni gbẹyin lara ife ẹyẹ naa lọdun yii.

Ko si idi meji fun eyi ju pe agbabọọlu ọmọ ilẹ Afirika mẹfa ọtọọtọ ni yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright @SpursOfficial
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ ree fun Tottenham ni ipele aṣekagba UEFA Champions league

Eyi si tumọ si pe ikọ yoo wu to ba bori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, ọmọ Afrika yoo wa nikalẹ lati gba ife ẹyẹ naa.

Fun ikọ Liverpool, agbabọọlu ọmọ ilẹ Afirika mẹrin lo wa ninu ikọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMyanmar: kékeré ni wọ́n ti n kọ́ àwọn ọmọ nípa ọ̀nà oge ṣiṣe

Agbabọọlu orilẹ-ede Guinea, Nabi Keita (lootọ oun ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ yii nitori o fara ṣeṣe), Sadio Mane lati orilẹede Senegal, Joel Matip lati orilẹ-ede Cameroun pẹlu Mohammed Salah to jẹ agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Egypt.

Fun ikọ Tottenham ni tirẹ, agbabọọlu orilẹ-ede Ivory Coast, Serge Aurier yoo wa n kalẹ lati darapọ mọ awọn ọmọ ilu rẹ bii Didier Drogba, Yayah Toure ati Solomon Kalou ti wọn ti f'igba kan ri gba ife ẹyẹ UEFA Champions League.

Image copyright @LFC
Àkọlé àwòrán Salah, Mane, Aurier, Wanyama yoo wọ ṣòkòtò kan náà láti gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions league ní ìlú Madrid

Bakan naa ni Victor Wanyama, ọmọ orilẹede Kenya naa yoo wa nikalẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham hotspur.

Odu ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ninu idije UEFA Champions league. Igba marun un ọtọọtọ ni wọn ti gba ife ẹyẹ yii; AC Milan ati Real Madrid nikan lo gba ife ẹyẹ yii ju wọn lọ. Real Madrid lo ṣi wọn lọwọ ninu awo ikẹfa ti wọn fẹ gba lọdun 2018.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú