NCC: A ti ri owó ti Iléeṣé MTN sannáà gbà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán MTN ti san owó ìtanran wọn tán fún Naijiria

Biliọnu ọgbọn lé ni ọọdunrun naira ni owó itanran ti Naijiria bù fún ileeṣẹ MTN.

Ileeṣẹ MTN jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to n ṣeto ibanisọrọ ni orilẹ-ede Naijiria yatọ si GLO, Airtel, Etisalat atawọn miran.

Àkọlé àwòrán Loṣu kẹwaa, ọdun 2015 ni NCC bu owó itanran to le ni tiriliọnu kan naira fun ileeṣẹ MTN.

Naijiria bu owó itanran yii fun ileeṣẹ yii nitoripe wọn ko tẹlẹ aṣẹ pe ki wọn re awọn onibara ti ko kopa ninu eto iforukọ silẹ tijọba pa kúrọ lasiko.

Ijọba Naijiria paṣẹ pe ki gbogbo ẹni to n lo ẹrọ ibanisọrọ forukọ silẹ ki wọn le gbogun ti awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram to n dunkooko ni Naijiria.

Àjọ Nigeria Communications Commission (NCC) to n mojuto ọrọ eto ibanisọrọ ni Naijiria fifidi ẹ mulẹ pe awọn ti ri ifitonileti banki lori owó naa gbà lọjọ Eti.

Loṣu kẹwaa, ọdun 2015 ni NCC bu owó itanran to le ni tiriliọnu kan naira fun ileeṣẹ MTN.

Lẹyin idunadura ni wọn wa din owó naa ku si ọgbọn biliọnu naira le ni ọọdunrun ni eyi ti wọn fun MTN lọdun mẹta lati san.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjọ NLC Naijiria : MTN kọ̀ jẹ́ kí òsìsẹ́ wọn darapọ̀ mọ́ àjọ òsìsẹ́

Bakan naa ni ileeṣẹ MTN ti darapọ mọ Nigeria Stock Exchange bayii to jẹ ọkan lara gbendeke ti ajọ NCC fun wọn nigba naa.

Ọpọ adanu lo de ba MTN lara awọn onibara to le ni miliọnu ọgọta ti wọn ni lọwọ lọdun 2016 tẹlẹ lataari sisan owó itanran yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMyanmar: kékeré ni wọ́n ti n kọ́ àwọn ọmọ nípa ọ̀nà oge ṣiṣe

Iroyin ni ileeṣẹ MTN ti wọn da silẹ lati orilẹ-ede South Africa yii ko tii yọ awọn onibara to le ni miliọnu marun un ti wọn ko kopa ninu iforukọ silẹ naa.

Egbẹrun owo dọla kan lori nọmba kọọkan ti MTN ko forukọ wọn silẹ ni ajọ NCC kọkọ sọ pe ki wọn san gẹgẹ bii owo itanran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBarister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa

Ki wọn to jọ sọ asọyepọ ti wọn fi din owo itanran naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Bayii ileeṣẹ MTN ti san owo itanran naa tán fún ajọ NCC Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMakinde: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ faramọ́ wíwọ́gilé ₦3000 táwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ń san