Oando bọ́ si abẹ́ ìwádìí àjọ eto aàbò okòwò àti pàṣípààrọ̀ Naijiria-SEC

Àkọlé àwòrán Oando bọ́ si abẹ́ ìwádìí àjọ eto aàbò okòwò àti pàṣípààrọ̀ Naijiria

A ṣi máa gbe ọrọ lọ si ọdọ FIRS, NSE ati CAC -SEC

Àjọ eto aàbò okòwò àti pàṣípààrọ̀ okòwò ní Naijiria (SEC) ti kede pe Wale Tinubu to jẹ oludari ileeṣẹ epo OANDO kò gbọdọ ṣe oludari ileeṣe ijọba kankan fun ọdun marun un.

Ajọ SEC ṣe ikede yii lẹyin iwadii ti wọn ṣe lori gbogbo kudiẹ-kudiẹ to ṣẹlẹ ninu awọn akọsilẹ ile iṣẹ naa.

Ajọ SEC tun fi ofin de igbakeji oludari ileeṣẹ Oando pẹlu pe iwa ti wọn hu na ko bojumu rara.

Ajọ SEC ni wọn fi ara balẹ ṣiṣẹ iwadii ileeṣẹ naa ti wọn fi lọlẹ labẹ Nigerian and Johannesburg Stock Exchange ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Elections 2019:Ìbò la ní kí ẹ dì, àwa kò bá tìjà wá

Bakan naa ni SEC tun paṣẹ pé ki gbogbo awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ to n ṣakoso ileeṣẹ ọhun tọrọ kan kọwe fipo wọn silẹ.

O tun ni wọn gbọdọ pe ipade gbogbo ile ni pajawiri ṣaaju ọjọ kinni, oṣu keje, ọdun yii ni kia.

Loju opo itakun agbaye SEC ni wọn ti ṣalaye ni kikun awọn magomago ati aifootọ ṣe akọsilẹ loriṣiiriṣii ti wọn ri ni OANDO.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́

Wọn ni awọn tun ri pe awọn ọmọ igbimọ n ṣe aṣilo awọn nkan ini ileeṣẹ naa ni eyi ti wọn ti paṣẹ pe ki wọn da pada bayii.

Ajọ SEC ni ki awọn ẹni kọọkan ati ileeṣe OANDO san owo itanran bẹrẹ lati ọdọ awọn oludari ileeṣẹ ọhun .

SEC tun ni ẹsun meji ti awọn ri gba lori ileeṣẹ yii lọdun 2017 lo bi iṣẹ iwadii ti awọn ṣe ni eyi to n bi eso itanran lasiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTinubu: Nítorí Tinubu, àwọn ọmọge Sanwo-Olu da ìlù bolẹ̀