Osun poly: Ọ̀pọ̀ òògùn, àti ohun eèlò ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣèwọ́de náà dá iná sun

Aworan Sheu Image copyright citymirror news
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ òògùn, àti ohun èlò ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣèwọ́de náà dá iná sun.

Akẹkọọ fò ṣanlẹ, o kú lẹyin idanwo.

Akẹkọọ onipele kẹta ileewe giga gbogboniṣe Poly ipinlẹ Ọṣun ni Iree kan, Aminu Sheu, ni iroyin sọ pe o ku lẹyin to pari idanwo aṣewọ ipele aṣekagba ẹkọ rẹ ni ọjọ Ẹti nilu Iree nipinlẹ Ọṣun.

Iroyin taa gbọ sọ pe, bi Sheu ṣe fi iwe idahun idanwo rẹ le awọn alamojuto idanwo lọwọ lo ba ṣubu lulẹ ti wọn si gbee digba-digba lọ si ileewosan.

Amọṣa, ẹpa ko boro mọ fun un nitori pe ileewosan ọhun lo dakẹ si lẹyin wakati diẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nitori eyi, n ṣe ni awọn akẹkọọ ileewe giga naa ya bo ileewosan to wa ni ọgba ileewe naa ti wọn si dana sun oko atawọn ohun elo miran to wa nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Ẹhonu awọn akẹkọọ naa ni pe aikun oju iwọn awọn oṣiṣẹ to wa ni ileewosan ileewe naa lo ṣokunfa iku akẹgbẹ wọn ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMyanmar: kékeré ni wọ́n ti n kọ́ àwọn ọmọ nípa ọ̀nà oge ṣiṣe

Amọṣa, ninu ọrọ to ba awọn oniroyin kan sọ, alukoro ileewe gbogboniṣe Poly Iree, Tọpẹ Abiọla ṣalaye fawọn akọroyin pe ko si ẹbi lọwọ awọn oṣiṣẹ ileewosan to jẹ ti ileewe naa.

O ni nnkan bii agogo mẹrin abọ irọlẹ ni wọn gbe e de ti awọn oṣiṣẹ iṣegun oyinbo to wa nibẹ si sa ipa wọn lati doola ẹmi rẹ ṣugbọn to ja si pabo.

Ọgbẹni Abiọla n ṣalaye siwaju sii pe wọn gbe akẹkọọ naa lọ sileewosan miran ni igboro ilu Iree nibẹ ni o si dakẹ si.

O ni 'Musulumi ni, o si n gba aawẹ Ramadan lọwọ. O ṣeeṣe ko jẹ pe aisi okun tó ninu lo faa to fi ṣubu to si daku."

Awọn akẹkọọ akẹgbẹ rẹ to ṣe iwọde lati fi ẹhonu han lori iku rẹ ni owurọ ọjọ Satide ko fojuure wo ileewosan ileewe naa rara.

Ṣe ni wọn dana sun awọn ohun Eelo, oogun atawọn ohun miran ti ọwọ wọn ba nibẹ lasiko iwọde naa.

Ọpọlọpẹ awọn oṣiṣẹ alaabo ileewe naa ni ko jẹ ki wọn raaye ati sun gbogbo ileewosan naa ni ina.

Lẹyin eyi ni awọn alaṣẹ ileewe naa ba gbe ilẹkun rẹ ti pa ti wọn si paṣẹ fun gbogbo akẹkọọ ki wọn maa gba ile obi ati alagbatọ wọn lọ.